Olootu Sports in Yoruba re e o!


image

Abolade Olajuwon Ryan re e, tani o mo o ri?

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Advertisements

Ronaldo ma n sise ju Messi lo- Henry


Abolade Olajuwon Ryan

Omo egbe agbaboolu Arsenal ati Barca tele tele Thiery Henry ti so oro nipa awon agbaboolu meji ti won soro nipa won ju bayi bayi.

Eti mo eni ti mo n so, Ronaldo ati Messi ni.

“Ronaldo sise kara kara lati de ibi to wa leni ni, koda Louis Saha ti won jo wa ni Man Utd na so fun mi wipe Ronaldo ni eni ti o man sise ni igbaradi won ju.

Henry to n gba boolu ni America bayi tu so wipe “mi ko so wipe Messi ki n sise asekara o, sugbon Messi ehn, ebun Olorun ni ohun fi de be.

“Messi man fi irorun gba boolu ni, ti awon omode ba n wo bayi, o ma n dun mo won ninu ni.

“Ronaldo ma n sise kara kara ko to le gba boolu, Messi ma n gba boolu pelu irorun ni” ni Henry ti o ba Messi gba boolu ni Barca so.

Ese ti kika.

Dani Alves fe na Messi pa


Brazil ni o ma gba alejo agbaye fun idije World cup ni ose meta to n bo.

Awon omo Barcelona meji, Lionel Messi ati Dani Alves ti so wipe awon ti ba ara won soro nipa idije World Cup, o si ma wu won ki won jo ko oju ija si ara won ni Final.

Orile ede lati South America meji, ni won fe ki o de idije ipari ohun, Brazil ati Argentina.

“Brazil ati Argentina ni mo fe ki o gba idije ipari” Dani Alves, omo orile ede Brazil ni o so be.

“Mo ti ba Messi soro nipa World cup, ireti wa ni wipe ki a jo pade ni Final, sugbon o da mi loju wipe mo ma naawon Messi.

“Igbekele mi wa ninu awon alayo orile ede Brazil nitori won dara pupo, itara ati gba ife eye yi wa laarin wa.

Ojo kejila osu kefa ni Brazil ati Crotia ma bere idije na ni Brazil.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Ore Messi ma kuro ni Barcelona


Lionel Messi, ti o sese ti owo bo iwe adehun tuntun pelu Barcelona, so fun Barcelona wipe ki won se eto adehun tuntun fun ore re na, iyen amule Barcelona, Gerard Pinto.

Messi je eni ti o ni itiju gidi gan, Pinto kedere je akorin ni Spain, ko ni itiju kankan, ko si eni ti Pinto ko lee ba soro tabi se ere pelu, eyi ni o mu fa oju Messi mora.

Pinto ati Messi ti je ore lati 2008 ti Barca ra a lati Celta.

Awon mejeeji jo ma n jade papo ni opolopo igba, lo si ojuse, ode ati ibi gbogbo.

Ise takun takun Valdes, ni ko je ki Pinto ri owo mu ni Barcelona, ti o so di igbakeji amule ni Barca.

Ise Pinto ko si te Barca lorun, ni won ba ni Pinto ma wa lara awon ti egbe na fe ru danu si igbo.

Ter Stegen, amule tuntun ti won sese ra lati Borussia Monchengladbach nikan ni amule ti o wa ni Barcelona bayi.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com