Awon ti won fe pa Madrid po o


image

“Mi ko fe koju Real Madrid nitori oju ti ma n wa lara boolu Champions league ti egbe meji lati Spain ba fe pade sugbon o wu mi lati gbesan nkan ti o sele ni odun meji seyin lowo won.”

Atletico fe gbesan, Bayern na fe gbesan, koda Man City na fe gbesan lara Madrid..

Advertisements

Awon aramanda to sele ni idi boolu


image

Ti e ba mo egbe agbaboolu Arsenal FC daada, e ma ti gbo wipe ‘The Arsenal’ ni a n pe won tele, kini o wa fa iyipada oruko won? Nigba ti ogbeni Herbert Chapman wa lori oye egbe agbaboolu na ni o yi oruko na pada si ‘Arsenal’ lasan.

Kini idi ti won se yi oruko na pada, ogbeni na lodun na fe ki Arsenal je akoko egbe ti won ma koko wa lori tabili ni ibeere sa tuntun. Eleyi ga o. Awon apere omiran ti o ga lagaju ni a ma so fun yin bayi. E tele mi ka lo.

Jean Langenus, adajo asikagba World Cup 1930, wo aso otutu, sokoto ti won fi n gba ‘golf’ ati aso ikorun pupa lati se akoso boolu na nigba yen. Eleyi tu ga o.

Ni odun 1996, agbaboolu Liberia, George Weah, san owo aso ati owo oko lati le je ki Liberia ko’pa ninu Nations cup lodun na lohun nigba ti won ko ri owo se eleyi ni Liberia. Hmmm!

Ni odun 1957, Huddersfield town ti n na Charlton Athletic ni ami ayo marun si okan sugbon laarin ogbon iseju ti o ku, Charlton bori won pelu ami ayo meje si mefa. Yeepa!

Idi ti a se n pe Pele ni Pele ni wipe Pele tumo si ese mefa ni orile ede Portugal, nigba ti a si bi Pele, ika mejila ni o ni, ika mefa mefa ni ese re mejeeji. Aramanda Eledumare!

Ni odun 1950, India yari lati gba world cup nitori won ko gba won laye lati gba boolu pelu ese lasan. Won sin gbere si ese ni?

Amule Arthur Wharton ni agbaboolu adulawo ti o koko gba boolu jeun. Ghana ni a ti bi, o si gba boolu fun Rotherham United ni odun 1889.

ASEC Abidjan, egbe agbaboolu orile ede Cote d’voire gba boolu ogorunlenimejo, won ko si ri enikeni ti o fi ya je won. Eleyi sele laarin 1989 si 1994. Baba kan ni ijebu lo ba won se ogun yen.

Ogbeni Carlos Caszely ni eni ti o koko gba pali pupa lori papa. Odun 1974 ni eleyi sele ni idije boolu agbaye. Omo orile ede Chile ni.

Opolopo ifarapa ma n waye ni boolu nitori ayo wipe won gba ami ayo wole. Eyan bi Celestine Babayaro kan ese re nigba ti o n dunu ami ayo re.

Babayaro yi na ni agbaboolu ti o kere ju to gba boolu ni Champions league. Omo odun merindinlogun ni ni igba na ni Anderlecht 1994.

STEFANO  Okaka Chuka ni eni ti o kere ju to gba boolu Uefa Cup, omo odun merindinlogun lohun na.

Ni osu kewa 1998, ara san pa awon alayo mokanla ti won gba boolu kan lati Democratic Republic of Congo, nkankan ko si se enikeni ni egbe keji. Ise sango niyen o, boya won se eyan kan.

GERMANY ni o ti gba ami ayo wole ju ni World Cup, ami ayo igba le ni merinlelogun.

Germany na si ni egbe ti o de Semi final ju, eleyi ni odun 1954, 1966, 1974, 1982, 1986, 1990, 2002, 2014. Ise niyen o!

Barcelona ni egbe ti o ti gba ife eye ju ni odun kan, ife eye mefa ni

La liga, Copa del rey, Spanish super cup, uefa champions league, European super cup, Fifa club world cup.

Egbe kan ni orile ede Madagascar Olympique L’Emryne gba ami ayo mokandinlaadojo ni odun 2002, won moomo se iyen ni lati polongo aise daada adajo ifesewonse ti won gba koja.

Michael Laudrup, agbaboolu kan, nigba ti Madrid na Barca ni ami ayo marun si odo, o gba boolu fun Madrid. Nigba ti Barca wa ra a, Barca na Madrid ni ami ayo marun si odo. Elese ayo marun ni bobo na.

Awon atileyin Maradona ni orisa kan pato ti won ma n bo.

Gbosa meje fun ogbeni Ajiboye Ariyo, awon ni won fun wa ni awon igbinmo yi ni ede geesi.

Fun awon igbinmo aramanda oro bayi, ki i se nipa boolu nikan o, e le darapo mo won lori BBM Amazing facts Channel won C001489CE. Eru ma ba yin.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and
http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Yaya Toure yaju si Agbalagba


image

O da bi wipe won ko fi omi to gbona jo awon mejeeji yi lenu, ikan kona ni won.

Oro rirun kan ni Toure so nigba ti Aubameyang gba ife eye.

Nigba ti Mikel gba Champions league, Toure ni won fun o, Mikel gba Nations Cup, ohun na ni o tu gba o, won wa fun Aubameyang nisin, o wa n se bi akan.

Ori re ti…….!

Asoju re na wa so bayi wipe Guardiola ko mo ise wipe awon egbe ti o n ko ko ni agbara ni.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and
http://www.twitter.com/sportsinyoruba