Abajade Man Utd tuntun


Okunowo Olawale Luffi

Manchester United ko fi igbakan gba boolu si oju ile nigba ti won gba Southampton ni
alejo ni Old Trafford eyi ti Dusan Tadic wa fi iya re je won gidi gaan.

Odun 2008 ni o ti sele gbeyin pe Manchester United ko ni fi eekan soso gba boolu wo
si oju ile awon ti won doju ko, eyi ti o si je wi pe ohun ti o sele ni Old Trafford
at wi pe 1988 ni o ti sele ri pe Southampton naa Manchester United gbeyin ni Old
Trafford gbehin.

Ni bi aadorin iseju ni Tadic gba boolu wo inu ojule lehin ti shoti ti Pelle gba ba
irin. Ni ooto ni Manchester United ta bio-bio lehin ti Southampton gba ami ayo kan
wo ile sugbon won ko se daadaa to lati bori ninu idije naa.

Toby Alderweireld ni o sese ninu idije yii, o si wa dabi pe van Persie fi ara pa lehin
ti o je wipe van Gaal yo ninu idije naa. Radamael Falcao ti o ti n te si oju ile lenu
ojo meta yii, ko kopa ninu idije yii eyi ti van Persie, Rooney ati Di Maria ko ri ona
lu aluyo.

Leyin idije yii, Southampton ti gun ori oke si ipo keta pelu ami ayo mokandinlogoji ti
won si wa ja United si ipo kerin pelu ami metadinlogun lehin ti gbogbo egbe inu BPL ti
gba idije mokanlelogun. Idije ti o kan bayii ni, Manchester United maa lo si Loftus road
lati koju QPR.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Advertisements

Iroyin tuntun ti Manchester United


Okunowo ‘Luffi’ Olawale

Ija fun ipo keta ni o ma wa ye laarin Manchester United ati Southampton loni ni Old Trafford

Ni Saint Mary Stadium ni bi ida yii ni osu ti o koja ni o je wipe awon omo Netherlands meji
fun egbe agba boolu meejeji ni won gba ami ayo wole, iyen Robin van Persie ti o gba meji wole
ati Graziano Pelle eyi ti Manchester United si jawe olubori ninu idije ohun pelu abajade 2-1

Ni owo asiko ti Manchester United bori yii ni won wa laarin igba ti won naa gbogbo egbe ti won
pade ni inakuna ti Southampton si n je iya gidi gaan laarin asiko yen. Manchester United ko
i ti so idije kankan nu lati igba yen naa sugbon ayipada ti de ba Southampton eyii ti won ko
i ti so idije kankan nu laarin maarun-un ti o koja si eyin.

Nje e le gbagbo wipe agba boolu kan sooso ni o sese laarin awon omo egbe United sha? Ooto ni o
oooo. Ashley Young nikan ni o ni asise ti awon oloyinbo n pe ni Hamstring injury. Eleyi ni
o tunmo si pe alakoso van Gaal fun igba akoko ni opolopo eniyan lati ju si nu awon ti won le doju
ko Southhampton loni. Ni aiye Southampton ke, Sadio Mane, Nathaniel Clyne won ko le fi be kopa
nitori ara won ko dan ga jiya to.

Idije yii ko ni derun bi Southampton se ma fe tiraka lati ma je ki Manchester United naa won mo
ile ati oode agaga ti ija bi omo iya ti o wa laarin van Gaal ati Ronald Koeman, sugbon ireti
wa wipe Manchester United a jawe olubori bi o se je wipe pupo ninu awon omo egbe agba boolu naa
ni o le ko ipa ti won ni oni.

Phil Dowd ni o ma se eeto idije naa ni oni ni Old Trafford ni bi aago marun-un, aago Nigeria.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Iroyin keresimesi Manchester United


Abajade idije laarin odun Keresimesi ati odun titun

Luffi

Ni aarin odun keresimesi ati odun tuntun,eyii ni
abajade awon idije ti Manchester United ni

P W D L GF GA Pts
4 1 3 0 5 3 6

Aston Villa 0-0 Manchester United
Manchester Utd 3-1 Newcastle Utd
Tottenham Hotspur 0-0 Manchester United
Stoke City 1-1 Manchester United

Laarin ami meerindinlogun ti o wa ni ile lati gba ninu asiko yii, mefa laasan nikan ni won
gbinyanju lati gba. Ti a ba ko gbogbo a po, United ko gbiyanju to rara! Asiko yii gaan pato
ni aye wa lati sun mo awon Manchester City ati Chelsea ti o wa ni iwaju. Eyi fi han nitori pe
awon egbe meji wonyi so awon ami nu laarin asiko yii eyi ti Manchester United o ba fi sun mo
won lati je pe won ma dije fun ife eye BPL.

Ninu idije ti Aston Villa ni Villa Park eyi ti o pari ni 1-1, Falcao ni o mu idije ma jabo ni owo
Manchester United lehin ti Benteke ti koko gba ami ayo kan wo ile. Idije kan sooso ti
Manchester United jawe olubori ni eyi ti won naa Newcastle ni 3-1 ni Old Trafford eyi ti
Rooney gba meji wole ti van Persie si wa fi keta wo le, leyin yii ni Phil Jones fun Cisse ni aiye
lati gba boolu wole ni oju ile.

Idije ti Tottenham ni White Hart Lane je eyii ti Manchester United ko ba ti pari ni aabo akoko
idije yii. Orisirisi aiye lati gba bi ayo bi merin wo ile ni awon omo egbe Manchester United
sonu sugbon o ye ki a gbe ojuba fun Hugo Lloris ti o tiraka lati di won ni ona ti idije naa si pari si 0-0.
Gboogbo eeyan ti o ma BPL daadaa ni o mo pe a ti lo ja ewe olubori ni Stoke City je nnkan ti o le gaan, sugbon ti
ko ba si aifarabale awon ti won di oju ile Manchester United mu ni, boya won ba ti gba ami ayo
meta kuro nibe sugbon idije yii si pari si 1-1 lehin ti Falcao naa tun pada wa gba ami kaan wole
leyin ti omo Manchester United tele rii, iyen Ryan Shawcross so di 1-0 nibi iseju meji si inu idije
naa.

Sugbon laarin aise deedee Manchester United naa, won ti lo ninu idije mewa lai fi idi remi bayii
eyi ti o je nnkan gidi ninu bi won se tiraka lati gba aiye won pada ninu idije Champions League
sugbon gege bi alakoso van Gaal ti se so, “ti won ba fe je eni ti o ma ja ewe olubori ni ipari
saa yii, won gbodo gbon awon egbe bii Stoke ati Tottenham danu lai se wahala pupo ni ile won.” Ireti ni
wipe gege bi oro re, nitooto Manchester United ma ma gun oke agba lo ninu odun titun 2015! Oju
gbogbo eniyan ma ma wo abajade idije won pelu Yeovil town ni ojo Aiku ti o n bo yii.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Man Utd ma gba EPL lowo Chelsea ati Man City nitori


Luffi

Àwon Manchester City àti Chelsea ti a fi ojú si lára pé wọ́n le gba ife ẹ̀yẹ Barclays Premier League ni ìgbèhìn sáà yìí ni won
se bí àgbà tí won naa àwon tìí won dojú ko ní ìparí ọ̀sẹ̀ ti o kojá yìí. Sùgbón se kò tún ti sí ẹgbẹ́ kẹta bayii?
Ẹgbẹ́ agbaboolu nàá ni Manchester United. Ẹ je kí a wo àwon nńkan tí o tókasí pe àwon nàá le tiraka làti gbà ifẹ BPL ni ọ̀tẹ̀ yìí

Lẹ́hìn ti alákòso van Gaal gba isẹ́ ẹgbẹ́ yìí ni o so wípé òhun ni láti fi bi osù mẹ́ta to Manchester United pò láti yege dáradára
sùgbón lẹ́hìn ti osù kẹ́ta yìí má pe, àwọn ẹgbẹ́ agbaboolu bi Swansea, Leicester ati MK Dons ni wọn ti fún United ní ìyà. Alákòso nàá wa yii ọ̀rọ̀ rè pada pe o ma tọ́ ọdún mẹ́ta.

Bi nńkan se n lo bayii, ọdún mẹ́ta yen lè ti pọ̀jù. Lẹ́yìn ti Man City tìí náà United ni 1-0 èyí tí o jẹ́ pe United ni o se dáadáa jù ní ọjọ́ náà, gbogbo ìgbà ni wọn ti n yege ni èyí tí wọn náà Crystàl Palace, Arsenal, Hull, Stoke, Southampton àti Liverpool. Àwọn ìdíje ti o kan bayìí láàrín ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun ni Aston Villa, Newcastle, Tottenham ati Stoke lẹ́ẹ̀kan si.

Nígbàtí tí o n bá MUTV sòrò, Wayne Rooney so wípé kò lè ju àwọn lo láti sá eré fún ifẹ ẹ̀yẹ yìí tí àwọn bá n já ewé olúborí ni àwọn ìdíje won lo. Ẹ̀yí fi han pé ìgbàgbọ́ ti padà sí àárín ẹgbẹ́ náà. Ipinnu a ti má sẹ abá́́yori nínú gbogbo ìdíje won je nńkan tó se pàtàkì làti se dáadáa èyí tí o tí n padà díẹ̀ díẹ̀ sí àárín ẹgbẹ́ naa.

̀̀Ìdí míràn tí a tun gbodò wò ni wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbaboolu náà pò èyí tì ó jẹ́ wípé tí èèyàn kan bá sẹ lẹ́sẹ̀, ení tí o ma dípò rè wàá pó ní ọ̀pọ̀ láì sí ìdíje míràn ti egbe naa n kopa ninu re. Yato si FA cup ti won ma dojú ko awon Yeovil Town ni ojo kerin osu to n bo, ko tun si nnkan miran ti o n da won laamu.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bi van Persie, Rooney àti De Gea, ti wọn ba lè ma se dáadáa bii wọ́n ti ń ba bò ni ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọ̀rọ̀ United lè fi ara pé ọ̀rọ̀ Liverpool ní sáà tí o kọjá yìí, wọ́n tún sì wa le se dára ju bé gaaan lo! Iye ìgbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbaboolu náà fí n dá lápá dá lẹ́sẹ̀ si gbọdọ̀ dínkù pátápátá.

Sùgbón, èyí tí o kan báyìí ni eré ti Villa Park tí wọn tí ma dojú kọ Aston Villa, bóyá láti ibi yìí ní ìtàn bii Manchester United se kúrò ní ipò kẹwàá ní ìbéèrè osù kọkànlá ti won si ma wa gba ife naa ni ìparí sáà yìi.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Asotele Manchester United ati Newcastle United


Lati owo Luffi

Ni aago merin oni ni Manchester United ma ni anfaani lati gba esan nina ti Newcastle na won
ni Old Trafford ni saa ti o koja.

Lehin ti alakoso van Gaal ti fun awon omo egbe agbaboolu re ni isinmi ni aaro ojo Keresimesi,
Oju gbogbo eniyan wa n wo bayii boya won ma le naa Newcastle ti Sunderland naa ni ose ti
o koja bayii

Awon ti won ko ni le kopa ni Fellaini, Blind, Shaw, Rojo ati be be lo nitori ifarapa ti n ba awon alayo United po poo lo ni saa yii. O si dabi pe awon alayo Newcastle naa si ni wahala ifarapa yi, eyii ti o je pe Jan Alnwick lo si ma di ile fun won ni ipo Elliot ati Tim Krul.

Abajade ere yii ko se gbekele sugbon Manchester United ti wa so Old Trafford di ile gidigba ti
egbe kankan ko i ti ri wan naa leyin ti Swansea ti naa won ni ojo akoko saa eyi ti a wa ninu
e yii.

Ireti waa pe awon bi Falcao, van Persie, Rooney ati Angel Di Maria ma bere ere boolu yii papoo.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Chicharito pada si Man Utd


Abolade Olajuwon Ryan

Nigba ti Real Madrid ya Javier ‘Chicharito’ Hernandez lowo Manchester United, odun kan ni wo ko sinu adehun, inu Chicharito si dun lati darapo mo Real Madrid to pe ni ‘egbe to dara ju ni gbogbo agbaye’, ko si wu lati pada si Man Utd fun oro ti o so yen.

Bayi, oro ti wo odi aso o, Ch14 ko gba boolu bi o se fe, bi o to le je wipe bi Man Utd na se nlo niyen, ko si alayo to fe wa lori ijoko. Ancelotti de so fun wipe bi awon se fe ma lo o niyen, ki o je igbakeji fu. Karim. Ki esi wa wo o, gbogbo ara ni Ch14 fi n sise nitori ko si irewesi ninu boolu re, ti won ba pe sori papa bayi, aramanda ni, die lo ma ku ti ko ba gba ami ayo wole.

Bayi, oro ti won so ni wipe Ch14 fe pada si Man Utd. E jowo, tani o fe lo gba joko nibe o? Se Rooney tabi RVP tabi Radamel ni?

Asoju re wa yoju si awon oniroyin ‘AS’, o so fun won wipe “woron woron ati isokuso awon oniroyin yi ti poju. O wu Hernandez lati gba boolu daadaa, o si mo wipe pelu ise asekara ati ore ofe, o ma ri boolu gba si.

“Ti eyan ba fe se oriire ni Madrid, o gbodo sise kara kara, Javier si mo eleyi, ohun gan si je eyan ti o feran ise asekara ni idi boolu.

“Ch14 ko fe kuro ni Madrid afi ti Man Utd ba so nkan omiran.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ayewo Manchester United Lat’owo Luffy


Luffi

Irohin abajade Aston Villa ati Manchester United

Falcao da ami ayo kan pada lati gba United ni owo Aston Villa

Pelu wipe awon ogbontagi agbaboolu Aston Villa bi Hutton ati Richardson ko kopa, Manchester United ko se bi oga ninu idije ti o wa ye ni Villa park. Benteke ni o ko gbo ina si oju ile nigba ti o gba boolu naa ni itosi ile ti o si fi Jonny Evans se ere die ki o to wa yii boolu koja De Gea.
Agbonlahor ni a lee danu kuro ninu ere naa nigba ti o kolu Ashley Young, Radamel Falcao si gba boolu sinu ile pelu ori re lehin ti Ashley Young sa boolu si oju ile.
Blackett, Wilson ati Di Maria ni awon ti United gbe wole ninu idije yii. Ipo keta ni United wa bayii pelu ami mejilelogbon. Idije ti o kan bayii ni Newcastle ni ojo keji odun keresimesi bayii.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ayewo Manchester United lat’owo Luffi


Okunowo Olawale Luffi

Abajade United ati Liverpool

Manchester United kan ese Liverpool

Ki ejo to poju, e je ki a koko sa atewo fun De Gea!!! Lai si ogbeeni yi ni oju ile, boya
itan miran ni a ba ma pa bayii! Ninu gbogbo e, igba mejo otooto ni o da awon omo egbe
agba boolu Liverpool duro, awon bi Sterling ati Balotelli. Rooney, Mata ati van Persie
ni won gba ami ayo kan-kan wo ile lati ja we olubori 3-0 ni Old Trafford.

Bi idije naa se beere ni Liverpool ti mu gbona fun United ni iseju mewa akoko inu idije
naa sugbon ko pe lehin ti De Gea da Sterling duro ni bi iseju mejila ni Valencia gba
aarin meji awon omo Liverpool meji koja ni o si te boolu naa si le fun Rooney ti iyen naa
si farabale te sinu ile.
O ku iseju maarun ki akoko aabo idije naa pari ni Ashley Young yii boolu sinu oju ile
Liverpool, eyi ti van Persie fi ori kan ki o to wa kan Juan Mata ti o fi ori yii wo ile.
Ni otoo, Mata yo ni ori ju gbogbo awon omo Liverpool nigba ti boolu naa kan van Persie
sugbon goolu naa duro lati 2-0 titi de aabo idije naa
Alakoso Brendan Rodgers fi Balotelli di ipo Lallana nigba ti ida keji ma beere, Balotelli
tiraka lati gba boolu koja ni ara De Gea sugbon paboo ni o ja si bi o se sele si
Sterling bi a se ri ti o je pe digbi ni De Gea duro ti o mu gbogbo boolu naa ti o si ikan
lu irin. Manchester United ni o gba iketa wole ni bi aadorin iseju nigba ti van Persie fi
si oju ile ni ofe.

Gbogbo awon ti won gba ninu idije ohun fun Manchester United ni won se daadaa, eyi ti o
fi di wipe United ti jade ni iwaju ninu gbogbo idije mefa ti won ti gba si eyin ninu
Barclays Premier League. Ipo keta ni United wa ni bayii ti won si n fi ayo meta la West-Ham
ti o wa ni ipo kerin.

Idije ti o kan fun Manchester United bayii ni Aston Villa ni Villa Park, eyii ti o je pe,
ti won ba tun le gbon ewuro si ni oju Aston Villa ni ile won, eyi ma a je idije keje ti
won ma ja ewe olubori ni sisentele, a le se wa ma beere boya Manchester United le gba ife
Barclays Premier Leaague ni opin re ni ote yii.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ayewo Manchester United


Okunowo Olawale [Luffi]

Ni saa ti o koja yii ni Liverpool gbo ewuro si oju United ni Anfield ati Old Trafford
nigba asiko ijamba Moyes. Sugbon osu mesan leyin, opon ti sun, Liverpool wa ni ipo kesan
ni ori tabili ti United si wa loke lohun ni ipo keta. Pelu eleyi, ko jo wi pe Liverpool
le da ara ni ote yii. Otoo ni wi pe United ko ta bio bio sugbon ipinu ati ja ewe olubori
ti a ri apeere re nigba ti won doju ko Southampton tun ti pada de eyi ti a fihan ni ara
Van Persie ti o dabi pe agbara re ti pada lenu ojo meta yii.
Awon ti won ko le kopa ni United ni Shaw, Blind, Smalling ati Di-Maria. Sibe naa, awon ti
won le dipo wa fun won wa lopolopo. O se se ki Balotelli gba ninu ere yii lehin igba ti
o darapo mo awon egbe re fun idaraya ni ojo eti.
Asotele abajade temi ni ori ere boolu yii ni wi pe o ye ki United ja ewe olubori sugbon
o buuru ju, ki o je pe won ma gba ami ayo kan na laarin won.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.