Ife boolu niwaju iku!


image

ABOLADE Olajuwon Ryan

Robert Lewandowski farapa pelu imu ati enu re nigba ti won padanu ifesewonse si owo Dortmund.

Robben ti yora re tele lara awon to fe ba Guardiola koju egbe re tele sugbon bayi Lewy na ti darapo mo o.

Dokita Bayern so wipe oro ti fi nkan omiran o, wipe Lewy koni kopa o.

Pelu eyi na, kini Lewy so? “Ojo ti a ma koju Barca si jina gan, o seese ki ara mi ti ya daadaa.”

Ese ti kika.

Advertisements

Ijaya MSN ni La liga


image

Abolade Olajuwon Ryan

Awon alayo meta yi to n gba iwaju fun Barca ti gba koja ami ayo ogorun fun egbe na ni iwoyi.

Messi (49),
Neymar (32)
Suárez (21)

Iyalaya enibodi to ba koju awon eleyi layi mura o.

Owo iya to ba Barca n gbe’mu si Real Madrid ati Atletico


image

Abolade Olajuwon Ryan

Bi FIFA se fi owo iya je Barcelona, awon oniroyin Cadena SER ati elero amititi Cadena COPE ti gbe iroyin si afefe wipe iru iya yen ma kan Real Madrid ati Atletico Madrid .

Ese wo ni won ka si won lese? Won ni Real Madrid ati Atletico n ra awon alayo odo omode ni ona ti ko to ati ti ko ye.

Odun kan gbako ni won ko ni fi ra alayo ti won ba ri daju wipe looto ni.

Ese ti kika.

Alonso – O seese ki Barca na Bayern pa nitori…


image

Abolade Olajuwon Ryan

Nkan ti Alonso so tele ni wipe ifesewonse Champions League laarin Bayern Munich ati Barcelona ko si lowo enikeni, wipe anfani aseyori wa laarin awon mejeeji ni.

Bi Lewy ati Robben se wa farapa bayi, Xabi ni “owo Barcelona ni opa ase ifesewonse na wa bayi nitori awon alayo pataki meji ti a padanu.

“Sibe sibe, enu ko ni won fi n se o, ki won wa f’arahan lori papa.”

Ija sese bere ni.

Ese ti kika.

Mourinho ati Henry so asiri fun Arsenal


image

Abolade Olajuwon Ryan

O tipe ti Arsenal ti wa ni ipo keji ni asiko yi ni sa EPL, afi ki won ma ba awon omode kan du akara ni ipo kerin.

Nigba ti Arsenal si n je Arsenal, ha! Eyin na mo… Okan lara awon alayo igba na, Thierry Henry so wipe o seese ki Arsenal dara bi asiko re ni Arsenal sugbon won nilo alayo merin otooto ti won dangajia gidi gan.

Henry ni lai se eyi, ki won gbagbe EPL. Mou si jeri si i wipe ooto ni.

Ese ti kika.

Isco ni Man City


image

Abolade Olajuwon Ryan

Lati ropo David Silva, awon oniroyin AS so wipe.  Man City fe ko milionu marundinlaadota le fun Francisco ‘Isco’ Alarcon.

Akoni moogba City, Manuel Pelegrinni je eni yi o sunmo Isco daada latari bi won se jo sise po ni Malaga.

Se o ye ki Isco darapo mo City lati Madrid?

Ese ti kika.

Ibo ni Guardiola ma wa ni sa to n bi?


image

Abolade Olajuwon Ryan

Alagbara kan, Klopp, ti kuro ni Bundesliga, Guardiola ni a n ro wipe o ma kuro bayi latari ijakule ti o seese ki o rigba lowo Porto ni Champions League ati wipe ko i ti t’owo bi iwe adehun tuntun pelu Bayern.

Guardiola wa so fun awon oniroyin wipe nkan to wa lokan ohun ni “ki n gbaradi, ki n sise mi, ki n si gba Bundesliga ti a ba koju Hertha.

“O si damiloju wipe mo ma wa ni Bayern lodun to n bo.”

Ese ti kika.