Akoni moogba Man Utd tuntun.


Abolade Olajuwon Ryan

Pelu gbogbo ijakule to n sele ni Real Madrid bayi, ki Ancelotti fi aye le lo fun elomiran ni won so o.

Nitori re ni Aare Real Madrid, Florentino Perez se jade so wipe igbekele ohun ati awon agbaagba Real Madrid duro digbin lori akoni moogba ati gbogbo alayo won, ko si si eni ti o ma le enikeni danu, igba yi a to koja.

Ancelotti to jewo wipe ohun feran aye ti ohun nje n Spain si n wo awon kan loju. Egbe meji ni ilu kan to n je Manchester ni orile ede England ni Europe ni aye yi ni won reti akoni moogba na ti o ba so wipe ohun da ise Madrid sile nisin.

Manchester United ati Manchester City ni won fe ki Ancelotti pada si England o, Ferguson gan ti fe Ancelotti tele, o si le ba a soro ti o ba wu Ancelotti lokan.

Madrid lo wu Carlo sugbon ti o ba da ise Madrid sile loni, ise yapa fun un o. Se mo paro ni?

Ese ti kika.

Advertisements

Kini itumo eleyi?


image

Ejowo, a nilo alaye.

Xavi jewo eni ti Messi n ba ja gidi gan


Abolade Olajuwon Ryan

Opelope akoni moogba Barca, Luis Enrique, ti o be Xavi ki o duro si Barca. Arakurin na ti fe ko eru re kuro ni Camp Nou. Akoni moogba Celta Vigo ati Roma tele na so fun wipe ohun si nilo re gidi gan.

Ilosiwaju ti wa ni Barca bayi ju ibeere sa yi lo, ope lowo omo kukute orile ede Argentina yi, Leo Messi. Ballon d’Or ikarun ni arakurin yi fe gba, o si ti bere daada fun ija ife eye na.

Xavi wa jewo wipe Messi n ba eyan kan ja, iyen si ni o mu ilosiwaju de ba a ni asiko yi. Tani eni na ti Messi n gbe ina woju re? “Messi fun’ra re no ni” ni Xavi so.

Mo wa bere lowo Xavi wipe kini itumo wipe Messi n ba ara re ja, awon oniroyin ‘Depor TV’ ni Xavi wa fun ni esi wipe “iyato wa ninu ki a ba eyan ja ati ki a na eyan pa. Ko si eni ti o ka’pa Messi lote yi ni, ohun ni alayo to dangajia ju ni agbaye, ko si elemi re, ohun ni o sese  wa n fun ara re ni oriyin ati itara lati gba boolu daadaa si.

“Nkan ti o wa dun ju nibe ni wipe Messi si kere, o ni anfani lati se daada ju bayi lo, idunu mi si ni wipe mo gba boolu ni egbe Messi ati nigba aye re”.

Ese ti kika.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Raul da si oro Real Madrid


Abolade Olajuwon Ryan

Ko si eni ti ki i koju wahala ni ile aye yi, Barcelona ti la ti won koja pelu ise asekara, Real Madrid ni o si kan bayi.

Bi o tile je wipe akoni moogba ojo iwaju Real Madrid Raul Gonzalez wa ni jina jina Cosmos, okan re si wa pelu Real Madrid daadaa, o si se akiyesi wahala to n lo ni Real Madrid lowo yi pelu wipe won ti gba ijoba aga lowo won.

”Inu mi baje gidi gan fun nkan to n sele lowo ni Real Madrid, awon ti araye n juba fun, fun aseyori ifesewonse mejilelogun lera ni osu melo kan seyin, won wa di eni ti wo n fi oju si lara fun ijakule won” ni Raul so fun awon oniroyin ‘Grupo Dutriz’ ni El Savaldor.

“Nkan ti o ko damiloju ni wipe Real Madrid ni awon alayo ti o le yi nkan pada si rere fun won. Gege bi atileyin won, mo fi edun okan mi ranse siwon, ki won tiraka lati se daadaa, won ma bori ijakule yi.”

Ese ti kika.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Omo Barca kan jewo eni ti o le se iku pa barca ni sonde…


Abolade Olajuwon Ryan

Nigba ti Abidal yege ninu ija re pelu aisan jejere, o lero wipe Barcelona ma je ki ohun tesiwaju ninu boolu gbigba re pelu won nitori ni t’phun o, ara ohun ti ya gaga sugbon o, awon agbaagba Barcelona ko fe ki o se ise wahala mo, won fe ki o fi boolu gbigba sile, ki o ma ba awon odo omode won sise.

Eleyi dun Abidal gan, o si pinu lati kuro ni Barca, ki o to kuro na, o fi ibanuje re han gidi gan. Sibe sibe, eyi ko mu ife Barca kuro lokan re, Barca na si nbuyi fun nigba k’igba to baye.

Imoran kan ni Abidal wa gba Barcelona bi o se ba awon alaworan ‘Gol tv’ so wipe “lowo yi, Benzema lo dara ju ni Madrid, ki i se Ronaldo rara.” Ami ayo ogun ni Zema ti gba wole ni sa yi ti ororo si ti gba mokanlelogoji wole.

image

“Looto ni wipe ti e ba le Karim kuro ni Madrid, Madrid si ma ma gba ami ayo wole sugbon ko ni po to bayi. Ti mo ba ni anfani lati ra alayo kan fun Barca, Benzema lo ma je. Ki i se nitori o je ore mi tabi araalu mi, nitori ise re ti o mo o se ni.

“Ni ojo sonde, Barca ma na Madrid ni ami ayo meta si okan, Messi, Suarez ati Neymar si ma gba ami ayo kan kan wole.”

ese ti kika.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Rooney juba re, Messi teriba fu un, kilosele?


Abolade Olajuwon Ryan

Ti araale ko ba pani, araata ko le pani. Eni ti o n bani gbe lo le s’alaye iwa eni to, afi ti o ba fe puro nikan.

Oro yi je be bi alayo Man Utd kan, Wayne Rooney, se wo amule England, Joe Hart susu ni ojo kan bi won se n gbaradi fun boolu England, ti o si so wipe ni tohun o, ko si amule to dara to arakurin Hart ni gbogbo agbaye yi.

Manchester City ni egbe agbaboolu orile ede England to ku ni Champions League sugbon awon na fi idi remi latari ami ayo meta si okan ti Barca fi iya re je won lori papa Etihad. Ivan  Rakitic wa ba gbogbo re je fun won bi ohun na se gba ami ayo kan wole lori papa Camp Nou.

Iba ma je opelope Joe Hart o, Man City ko ba je to mejo lano. Messi sa agbara re to sugbon pabo ni gbogbo re jasi bi Hart se n pari gbogbo re si’gbo.

Eyi lo wa mu Messi teriba fun amule na nigba to ba awon oniroyin ‘UEFA.com’ soro wipe “babanla ise ni Hart se loni o, emi ti mo tele wipe oganla amule ni Hart sugbon pelu aramanda to tu gbe yo loni, sasa ni amule tio le mu gbogbo boolu ti o mu.”

Boolu mewa ni a ka ti Hart ti danu lati owo awon alayo Barcelona sugbon ko to lati gbe won lo si abala quater-final.

Ese ti kika.

BBM : 534E8D29
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan si wa ni sportsinyoruba@gmail.com.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa ni
http://www.facebook.com/sportbouquet and http://www.twitter.com/sportsinyoruba

Suarez – Real Madrid daran, mo ti mo ibi ti mo ti ma mu won, ohun si ni….


Abolade Olajuwon Ryan

Bi Barcelona se fe koju ija si Man City ni ale yi lori papa Camp Nou, awon alayo Barcelona n dibo wipe awon ko gbe Real Madrid s’okan, wipe Man City ti won ti na pa ni awon gbe s’okan, lara won ni Iniesta.

Sugbon o, eleyin ayo, Suarez, jewo wipe El Clasico wa ni okan t’ohun o, idi re si ni wipe ohun ti se iwadi tire lati ri daju wipe awon fi idi Real Madrid gbo’le.The 'Clásico' is a final

Gbogbo wa la mo wipe El Clasico ni ifesewonse ti agbaye n wo ju, Suarez si so wipe “ifesewonse ojo sonde yi ma talenu gidi gan, gbogbo agbaye ni o ma a wo, o si ma fun mi ni itara lati gba boolu pelu igboya to pe ye.”

Gbogbo wa la si ranti isele sa 2010/11 ti Madrid je buruku iya ni Camp Nou, ami ayo marun si odo, Suarez so wipe “mo wa lori papa ni ojo ti Barca fi eyin won gbo’le nitori mo wa wo’ran, bi inu awon atileyin wa se dun lojo na lohun si n yamilenu, iru re ni mo fe ki o tun sele.

“Mo mo wipe oganla kan ni Real Madrid sugbon o, mo mo ibi ti won ku si leyin won yen. Eyin won ko dara to, ibi ti mo de ti ma se won pa niyen.

“Mi ko gbadun ara mi to ni ifesewonse El Clasico alaakoko sugbon ni ote yi, iyalaya enibodi, won ma gba!”.