Tani o ye k’a da lebi fun ijakule Real Madrid yi?


Abolade Olajuwon Ryan

Lowo yi, e gbagbe wipe asise ni Atletico fi n na Real Madrid, tabi o kan bo siwon lowo ni. Haba! Ifesewonse mefa lera, Madrid ko si ri owo mu ninu eyo kan pere. O ti fe mora nisin wipe Atletico ti mo owo Real Madrid bayi, se won sin gb’esan Champions League tabi awon alayo Madrid to farapa la ma so wipe o fa ijakule yi? Ko fe ye Ancelotti mo o.

image

Awon oniroyin Spain ‘Marca’ wa bere lowo awon awon atileyin Real Madrid wipe tani won ma da lebi fun ijakule na, kini won so?

Awon merin otooto ni won da lebi, ikini ti won so wipe o gba iranu ju ni Cristiano Ronaldo, Sami Khedira ni won so wipe o gba osi tele ti Iker Casillas ni won mu se iketa.

Oga won, Carlo Ancelotti ni won mu se ikerin nitori won lero wipe ko si nkankan ti opolo re le se ni ifesewonse na.

image

Bi Atletico se gba ami ayo ikini wole,  ti osi sele nitori asise amule won Casillas ni awon atileyin Real MADRID TI N PARIWO “IKER..IKER” lati fi han wipe ohun ni asise ti owo re wa o.

Ti Madrid ati Atleti ba tu ma pade ni sa yi, o tu di Champions League, nje eyin lero wipe apa Madrid a ka won ni igba na?

Ese ti kika.

Leave a comment