Iniesta – Aye Barca ti baje looto…


Abolade Olajuwon Ryan

Tani o ranti Barcelona ni aye Guardiola? Tani won bi da? Iyalaya enibodi! Iya…babanla iya lo ma ba nibe.. Ta’lo to be lati gbe ina w’oju ekun? Sugbon ese melo lo wa laye? O da bi wipe won so wipe ese mefa! Gege be egbe APC…’Change’ gbodo sele.

Nkan to de ba Barcelona niyen, bi awon fun ra won gan ko ba mo, awa mo. Igba kan ni Madrid gan yege fun igba to pe, leyin odun melo kan, iya bere si ni bawon, ki won to na owo, paro akoni moogba, ra alayo lo..ta alayo lo. O sa di igba kan, won pada, won gba ‘La Decima’. Bi ile aye se ri niyen, Barca si ma pada sugbon o seese ki o pe die.

Andre Iniesta, alayo Barcelona ti gba wipe odun 2014 je odun to buru jayi fun Barcelona, sugbon awon ti setan lati gbagbe gbogbo osi yen, won si fe fi odun 2015 dun awon atileyin won ninu.

Awon oniroyin ‘Sport’ ni Iniesta so fun wipe “looto ni wipe aye Barca baje pelu ifaseyin 2014, o wu wa lati gba ife eye repete bayi sugbon a ko le se ileri ife eye fun enikeni, nkan ti a le se ni ki a sa tiraka, ki a sa agbara wa.

“Gbogbo wa ni Barca maje ki inu awon atileyin wa dun gidi gan, ifaseyin temi tu le nitori ifarapa mi. Sugbon mo fi n da yin loju wipe Barcelona n bo lati ya yin lenu, emi gan ma f’akoyo lowo ta wa yi.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Advertisements

Bale yaka si Man Utd nitori…


Abolade Olajuwon Ryan

Ija kan ti koko sele laarin Gareth ati Jose. Bale so wipe La liga dara ju EPL sugbon Jose Mourinho so wipe EPL dara ju La liga. Nigba ti Mou wa ni Madrid, o so wipe La liga dara ju EPL lo ati wipe ti won ba gbe Real Madrid ati Barcelona wa si EPL, awon ni won ma se ipo kini ati ikeji. Mou ti gbagbe ni.

Bayi, leyin ogorun milionu pon ti Real Madrid na si ori Gareth Bale, ti o wa papa wa ni egbe agbaboolu ti o nife si lati kekere, awa gbo wipe Man Utd ti ko gba boolu ni Champions League fe fa seyin. Ogbeni na taka osi danu, koda o yaka si Man Utd ni.

Awon oniroyin ‘Marca’ ni Bale so fun wipe “Man Utd ko, Man Utd ni. Mo feran Madrid baje baje, mo feran afefe ilu yi, mo feran gbogbo osise Real Madrid. O wu mi lati gba ife eye repete pelu Madrid.

“2019 ni adehun emi ati Madrid pari, idunu mi si ni o ma je lati tesiwaju ju be gan lo.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Man Utd ma gba EPL lowo Chelsea ati Man City nitori


Luffi

Àwon Manchester City àti Chelsea ti a fi ojú si lára pé wọ́n le gba ife ẹ̀yẹ Barclays Premier League ni ìgbèhìn sáà yìí ni won
se bí àgbà tí won naa àwon tìí won dojú ko ní ìparí ọ̀sẹ̀ ti o kojá yìí. Sùgbón se kò tún ti sí ẹgbẹ́ kẹta bayii?
Ẹgbẹ́ agbaboolu nàá ni Manchester United. Ẹ je kí a wo àwon nńkan tí o tókasí pe àwon nàá le tiraka làti gbà ifẹ BPL ni ọ̀tẹ̀ yìí

Lẹ́hìn ti alákòso van Gaal gba isẹ́ ẹgbẹ́ yìí ni o so wípé òhun ni láti fi bi osù mẹ́ta to Manchester United pò láti yege dáradára
sùgbón lẹ́hìn ti osù kẹ́ta yìí má pe, àwọn ẹgbẹ́ agbaboolu bi Swansea, Leicester ati MK Dons ni wọn ti fún United ní ìyà. Alákòso nàá wa yii ọ̀rọ̀ rè pada pe o ma tọ́ ọdún mẹ́ta.

Bi nńkan se n lo bayii, ọdún mẹ́ta yen lè ti pọ̀jù. Lẹ́yìn ti Man City tìí náà United ni 1-0 èyí tí o jẹ́ pe United ni o se dáadáa jù ní ọjọ́ náà, gbogbo ìgbà ni wọn ti n yege ni èyí tí wọn náà Crystàl Palace, Arsenal, Hull, Stoke, Southampton àti Liverpool. Àwọn ìdíje ti o kan bayìí láàrín ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun ni Aston Villa, Newcastle, Tottenham ati Stoke lẹ́ẹ̀kan si.

Nígbàtí tí o n bá MUTV sòrò, Wayne Rooney so wípé kò lè ju àwọn lo láti sá eré fún ifẹ ẹ̀yẹ yìí tí àwọn bá n já ewé olúborí ni àwọn ìdíje won lo. Ẹ̀yí fi han pé ìgbàgbọ́ ti padà sí àárín ẹgbẹ́ náà. Ipinnu a ti má sẹ abá́́yori nínú gbogbo ìdíje won je nńkan tó se pàtàkì làti se dáadáa èyí tí o tí n padà díẹ̀ díẹ̀ sí àárín ẹgbẹ́ naa.

̀̀Ìdí míràn tí a tun gbodò wò ni wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbaboolu náà pò èyí tì ó jẹ́ wípé tí èèyàn kan bá sẹ lẹ́sẹ̀, ení tí o ma dípò rè wàá pó ní ọ̀pọ̀ láì sí ìdíje míràn ti egbe naa n kopa ninu re. Yato si FA cup ti won ma dojú ko awon Yeovil Town ni ojo kerin osu to n bo, ko tun si nnkan miran ti o n da won laamu.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bi van Persie, Rooney àti De Gea, ti wọn ba lè ma se dáadáa bii wọ́n ti ń ba bò ni ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọ̀rọ̀ United lè fi ara pé ọ̀rọ̀ Liverpool ní sáà tí o kọjá yìí, wọ́n tún sì wa le se dára ju bé gaaan lo! Iye ìgbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbaboolu náà fí n dá lápá dá lẹ́sẹ̀ si gbọdọ̀ dínkù pátápátá.

Sùgbón, èyí tí o kan báyìí ni eré ti Villa Park tí wọn tí ma dojú kọ Aston Villa, bóyá láti ibi yìí ní ìtàn bii Manchester United se kúrò ní ipò kẹwàá ní ìbéèrè osù kọkànlá ti won si ma wa gba ife naa ni ìparí sáà yìi.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Eeyah!! Inu Barcelona baje ni Dubai


Abolade Olajuwon Ryan

Ha! O ma se o! Atileyin Barcelona ti inu re ba dun si eyi, nkan omiran to wo o. Igbakan ni inu Real Madrid ma n baje bayi sugbon ‘La Decima’ ti won gba yi si iwe rere fun won ni. Kilosele?

Ni ayeye Globe Soccer Awards to sele ni Dubai, ife eye mefa otooto ni Real Madrid gba. Awon ife eye wo ni won gba?

Egbe agbaboolu to dangajia ju ni odun 2014 – Real Madrid CF

Aare Egbe agbaboolu to dangajia ju ni odun 2014 – Florentino Perez (Real Madrid)

Alayo ti a feran ju lori iwe iroyin ‘Marca’ – Cristiano Ronaldo (Real Madrid)

Irawo tuntun odun 2014 – James Rodriguez (Real Madrid)

Alayo to dangajia ju ni odun 2014 – Cristiano Ronaldo (Real Madrid).

Milan ati Real Madrid ma koju ija si’ra loni fun onigbowo won ‘Emirates’ ni Dubai lati pari odun yi.

Barcelona nkan? Oma ga o… Barca na n pada bo, igba die na ni, won lo sinmi oriire ti won se seyin ni.

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Xavi ni Real Madrid


Abolade Olajuwon Ryan

O ku die, Xavi ko ba kuro ni Barcelona fun idi wipe Barca ko gba nkankan ni sa to koja ati ijakule Spain. O pinu lati fi boolu Spain ati Barca le, pelu iranlowo Oluwa, o fi ti Spain le, Enrique si ba soro gidi gan wipe awon si nilo re ni Barca.

Xavi gba, bayi bayi, inu re si dun pelu ipinu re ati wipe ohun ko ni tele ilana Figo ati Ronaldo to fi Barca le fun Madrid.

Awon asoju-ko’royin kan ni Egypt ni Xavi so fun wipe “Madrid ke, kojo! Ko jo rara! Okan mi ko le bale nibe nitori eje Barca lo wa ninu mi.

“Boolu afesegba yi ni gbogbo igbesi aye mi, mi ko le fi ropo nkankan, mo si wa ni ibi ti mo feran. Inu mi dun wipe mi ko fi Barca le. Ti n ba feyinti, o wu mi lati di akoni moogba tabi asoju boolu Barca. To ba sa ti je nipa boolu, okan mi bale.

“Mi ko fe fi Barca le, koda, o wu mi lati feyinti ni Barca bi o ti le je wipe ma a joko die.”

Nipa ijakule Barca, Xavi ni “asiko Guardiola dun, igba Tito si rorun die. O ma le lati gba ife eye bi ti Guardiola sugbon a ma gbinyanju sa.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Neuer jewo bi Bayern se fe gbesan Chelsea


Abolade Olajuwon Ryan

Tani o ranti asekagba odun 2012 ti idije Champions League ti Chelsea na Bayern lati gba ife eye akoko won ninu idije na? Se e ranti bi Drogba se fi ori da ami ayo Muller pada ki won to na won pelu Penalty? Nkan to duni ju loro yen ni wipe ile Bayern Munich, Allianz Arena ni Chelsea ti na won.

Odun to tele, Chelsea gba ife eye Europa League, Bayern si gba Champions League, eyi to mu awon mejeeji pade ni European Super Cup pelu akoni moogba tuntun meji. Guardiola sese de si Bayern bi Mou se pada si Chelsea. O ku die ki Chelsea bori, koda Mourinho ti n juwo bi eni to yege sugbon Bayern dapada, won si na won pelu Penalty. Afi bi ti Chelsea lodun na lohun.

Eleyi ko i ti dun mo awon alayo Bayern to, won ko i ti gbagbe isele yi, ni amule se wa salaye igbese won. Ori papa Berlin ni UEFA mu lati gba asekagba Champions League ti sa yi, orile ede Germany lo si wa. Neuer so wipe “niwon igba ti a ko i ti gbagbe iya ti Chelsea fi je wa, ti a padanu ife eye lori papa tiwa gangan,.a ti setan lati gbesan bayi, a ma sa gbogbo agbara wa lati ri wipe a gba ti Berlin yi to je ti UEFA ni ki won wa gba ni orile ede wa.”

Igba wo ni Neuer ma wa feyinti? “Mi ko mo o, ojo si wa niwaju mi gidi gan, leyin Paris 2016 gan, ori mi si ma wa nibe. Ti won ba sa ti n lo mi, ko si were.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Mourinho ni Barcelona


Abolade Olajuwon Ryan

Mourinho sise ni Barca ri, ki Guardiola si to debe bi akoni moogba, Mou ni awon agbaagba Barca pe lati gba ise na. O fun won ni ogbon 4-3-3 ti won si jeri si, eleyi ti Guardiola lo ju.

Fabregas to ti gba boolu gege bi ore ati ota Mourinho lo wa n ja wa si wipe “ti Mou ba lo si Barca, o ma se oriire gan.

“Eleyi je be latari wipe isesi gba boolu Barca ko yato si ti Chelsea.” Se looto niyen sa? “Mou si ti jasi isesi yi daadaa pelu iriri to dangajia.

“Ni Chelsea bayi, a n di boolu mu, a fe ma se asiwaju ati adari ni gbogbo ifesewonse wa, agbekale wa le yato sugbon ikan-kan-na ni pelu ti Barca.” Eni to ti gba boolu fun awon mejeeji na lo le soro yi.

“Idi ti Mourinho de se ma tete r’owomu ni Barca ni wipe o ma n tete mo owo awon alayo re, o si mo bi o se le je ki alayo gba ipo repete. Eyan ti o si ni opolo ni o le se eleyi. Pelu eyi, Mou ma se oriire ni Barca.”

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Tani o gba ebun wa?


Abolade Olajuwon Ryan

Ogbeni Foladayo ni won gba, a si ti fi ebun na ranse si won pelu 07063541177.

Ese gan.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ejowo


Abolade Olajuwon Ryan

Ejowo, a ko ni si ni’le titi di ojo aje, e ma binu o, ise na lo gbe wa lo o. Eni ti o je ebun gbeyin, a ko gbagbe yin o. Ese gan.

Ese

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Yeepa! Neuer tasi FIFA, Messi ati Ronaldo


Abolade Olajuwon Ryan

Nigba ti won fun Messi ni boolu wura leyin idije World Cup fun alayo to se daadaa ju, awon eyan soro gan, koda, eni ti o je bi baba fun Messi, alayo ati akoni-moogba Argies tele Diego Maradona so wipe ife eye yen ko to si, wipe FIFA fun Messi ki o le ba won p’olowo ni, bi wipe Messi ma mu owo wole ju gbogbo awon alayo to gba asikagba yen lo.

Eleyi tumo si wipe ti alayo ba fe gba ife eye adani, ki i se nipa ise asekara nikan, eni na gbodo lenu bi ‘kettle’ ki owo le ba wole fun FIFA.

Eyi lo mu amule Bayern ati Germany, Manuel Neuer ti a mu pelu Messi ati Ronaldo lati ja fu ife eye Ballon d’Or so awon oro yi.

“Oriyin nla ni fun mi lati wa lara awon meta ti won fe ja fun Ballon d’Or yi, sugbon Messi ati Ronaldo n anfani lati gba ife eye yi nitori won lenu ju mi lo” ni o so fun awon oniroyin ‘Suddeutsche Zeitung’.

“FIFA le fe fun won nitori owo ti won fe pa lori won.”

Se ooto loto yi?

Ese ti kika.

Enikeni ti o ba ni ounka tabi aroko yoruba le kan si wa o.
BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.