Mourinho tasi Ronaldo, Hazard, Fabregas ati Real Madrid nitori…


Abolade Olajuwon Ryan

Ballon d’Or t’odun 2012, Jose Mourinho, akoni moogba Chelsea to wa ni Madrid, ko lo o, o so wipe ohun ni ise lowo ni ohun ko se lo sugbon iro ni, o mo wipe ohun ko ni gba a ni, o daju wipe Del Bosque lo to si. Mou gba ni 2010 sa fun aseyori re ni Inter.

Sugbon loro kan sa, Mou fi han wipe ohun ko fibe gba ti Ballon d’Or nitori o ma n polowo adagba ti o si n ba boolu je.

Bi Platini ati Madrid ni ija die, Mou na soro nipa nkan na.

“Ife eye yi ma ba boolu je ni, ko dara fun boolu rara” ni Mou so fun awon asoju-koroyin, “idi ti mi ko se gba tie niyen.

“Mi ko fe awon alayo mi gbe sori bi Ronaldo bi o tile je wipe Hazard ati Fabregas ni ore ofe lati gba ife eye na.

“Mo fe ki won foju si ise won ni Chelsea, ki won ma fi ero ife yi da Chelsea ru pelu adagba.”

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Advertisements

Guardiola jewo eni ti o le pa oruko Messi re ninu itan. tani?


Abolade Olajuwon Ryan

Awon aseyori kan wa to je wipe eni to se gan ma ni l’okan ara re wipe ko si eni ti o le ba’aje sugbon e je ki n so kini kan fun yin, ko si nkan ti eyan ma se ti enikan ko ni se ju be e lo. Enikan ti a ko le se bi tie nikan ni Eledumare.

Sugbin niwan igba ti o ti je wipe eyan lo se aseyori yen, Olorun funra re ma da eni ti o ma ba kini ohun je. Guardiola gan jasi oro yi.

Ni aye ti a wa yi, Ronaldo ati Messi ni Olorun da lati ma pa awon oruko awon alayo atijo seyin. Be tie bu won, ase Olorun ni, Olorun ti fun won ni ore ofe lati pa awon oruko yi re ni.

Sugbon bi awon na se n pa awon oruko alayo re nisin, lojo kan na, alayo kan na ma pa oruko awon alayo yi re. Messi ni eni ti o se bebe lasiko yi ni akoni moogba re tele ni Barcelona Pep Guardiola se so wipe “oriyin nla ni aseyori yi je fun Messi, a gbodo ki i ku orire. Ise nla lo se lati fi de ibi giga yi i.

“Aseyori to se yi, nkan ti a ko lero wipe o ma sele ni, o si ti se e, ogota odun ni oruko Zarra ti wa nile, Messi gbiyanju.”

Tani o ma wa pa oruko Messi re? Guardiola so wipe “eni ti o ma paare wa, sugbon Olorun ko i ti da a ni, odun ogorun mefa ni o ma gba eyan lati se iru nkan ti Messi se yi nitori Messi si ni bi odun mewa lati gba boolu fun Barca, o si ma gba ami ayo repete wole si i.”

Ki a ma paro, eni yen ni ise lati se e sugbon o ma se ise na..dandan.

Guardiola si so wipe “idunu mi ni fun Messi lati pari igbesi aye boolu re ni Barca.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Real Madrid so oro buruku si UEFA nitori…


Abolade Oajuwon Ryan

Nkan ti Ballon d’Or yi ma dale sa! Mo lero wipe ona ati ona kan lati FIFA ru ni Platini n gba yo yi, nitori aare UEFA na so jade wipe omo orile ede Germany ni FIFA gbodo fun ni ife eye na. E jowo e ba mi bi Platini lere ibere meta.

Ikini, ki lo kan nibe? Eleekeji, igba ti awon fe fun ife eye UEFA Player of the year, kilode ti won ko se fun alayo Germany, kilode ti awon na se fun Ronaldo nigba ti won ro wipe ko to si? Ibeere keta ni wipe sebi Ballon d’Or wa fun alayo to ba se daadaa ju ninu egbe kan ni, ti gbogbo egbe ba se daadaa, won ma gba ife eye won ni sugbon Ballon d’Or wa fun alayo kan soso ni, to ba se daadaa l’odun kan. Idi ti Messi se gba a ni odun 2010 niyen pelu wipe Spain gba World Cup.

Bi Platini se so oro yi, inu bi gbogbo alayo, olori, ifun ati edo Real Madrid, ni won ba ko iwe iranse si Platini wipe oro to so jade lati yan eyan kan ko ba ilano gbajumo lo, wipe Ballon d’Or ko si nipa egbe sugbon nipa alayo kan soso, wipe awon si ro wipe Ronaldo lo to si, iyen ti won ba tele ilana ti won gbe kale o.

Ki ori won ya pe o ni Madrid so fun won o, ki won si fun eni ti o to si. Won tu fi han wipe awon wa leyin Ronaldo bi ike ni. Arbeloa ati Coentrao wa so wipe ki Platini ye se nkan ti awon to ma dibo ma fi ko’rira CR7.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Fabregas jewo idi ti Chelsea se dara ju Barcelona ati Spain gan lo. o ni…


Abolade Olajuwon Ryan

Fabregas ti se iranlowo fun awon alayo Chelsea to n gba ami ayo wole gan, Fabregas wa fi Chelsea we Barcelona ati Spain, awon asoju-koroyin ni o ba so oro wonyi, ki lo so?

Fabregas fi ipo ti o n gba fun Chelsea we ipo to gba fun Barca ati Spain. Mou gan ti so tele wipe Barca ati Spain ko mo Fabregas lo daadaa.

Fabregas na wa so nisin wipe “mi ko ro wipe mo gbadun boolu ri i bi mo se n gba boolu ni Chelsea yi. Nigba ti mo dojuko awon eyan ni World Cup Final gan, Champions League na sugbon mi ko gbadun ara mi to bayi.

“Westbrom ati Schalke yi, mo gbadun ara mi gan bi o ti le je wipe egbe pepepe ni won. Nigba ti mo wa si Chelsea, mo ni lokan lati se oriire ati lati gbadun ara mi. Sugbon awon igbakan wa ti mi ko ni gbadun ara mi.”

Bawo ni o se wa kan Barca ati Spain? Cesc ni “ipo iwaju ti mo n gba fun Barca ati Spain, mo kan n gba ni, ko dun mo mi ninu to. Sugbon ni Chelsea, ipo aarin ti mo n gba ni Chelsea bayi, o gbayi gan ni! O mo mi lara, o si ma je ki n le ran Chelsea lowo daadaa.

“Ipo yi ma n je ki n dari boolu, inu mi si ma n dun si. Ti n ba lo si iwaju, Oscar le dipo mi, mo ni ominira, nkan ti mo si feran ju lori papa niyen.”

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Reus ni Chelsea…Mourinho so wipe…


Abolade Olajuwon Ryan

Tani ko gbo wipe Reus n bo ni Chelsea ati bi Mou se fe ja gba lowo Madrid? Tabi…..bi Mou se fe fi milionu mewa lodun fa oju re wa si Stamford Bridge?

Akoni moogba Dortmund Jurgen Klopp ti salaye layipe yi wipe Marco Reus ma kuro ni BVB, Chelsea si la gbo wipe won tejumo bobo na sugbon baba agba Chelsea Jose Mourinho ti so bayi wipe “a ko nilo Reus rara, ko si ninu adehun Chelsea rara, oruko yen gan ko si laarin iwe wa.” Yeeparipa!

Bi won kuku se ma n so niyen ki a to sadede ri alayo na laarin won sugbon nkan ti Mou so fun wa bayi niyen o.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Wenger kanra mo olori Arsenal nitori…


Abolade Olajuwon Ryan

Pami si’le, ma pami si’ta lo n bi Wenger ninu bayi. Ta lo n pa tani gan?

Pelu bi Man Utd se na Arsenal, igbakeji olori Arsenal, to ni eto ju ni Arsenal, Alisher Usmanov lo fi itara re han si awon oniroyin wipe iwa Wenger ti ko fe nawo gangan ni o n se okunfa iresile Arsenal yi.”

Milionu to ku die lati to ogorun ni Wenger na ni asiko kara-kata yi, o tu pinu lati ra awon alayo si i ni osu kini odun to n bo.

“Mi o ran baba yen nise jare” ni Wenger so fun awon asoju-ko’royin, “eleyi ko si jomi loju nitori emi na ti pe ni ibi die.

“Onikaluku lo l’anfani lati so ero okan won sugbon o ye ki a ma so enu wa ti a ba n soro lati ri wipe a ko ba enikeji wa je.

“O ye ki Usmanov pami sile ni, ko nilo ati polongo lo ba awon oniroyin.”

Ipo kejo ni Arsenal wa lori tabili bayi.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Giggs – Man Utd kere si nomba Chelsea bayi nitori…


Abolade Olajuwon Ryan

Pelu ifesewonse mejila ni Premiership ti ko i ti si egbe agbaboolu to ti fi eyin Chelsea gbo ile, igba keji akoni moogba Man Utd Ryan Giggs ti so fun gbogbo awon egbe agbaboolu to wa ni England ya fa sokoto won daadaa nitori eni ti o ba fe na Chelsea l’ote yi, o di dandan ki o gba oke olumo lo lati lo ri awon agba.

Awon oniroyin ‘Sky Sport’ ni omo orile ede Wales to gba ife eye Premiership metala wipe “gbogbo yin le ma gba wipe lowo yi, gbogbo egbe agbaboolu England kere si nomba Chelsea lowo yi.

“Sugbon, a ko gbodo repete o, a gbodo tiraka lati de ibi ti won wa ki a si koja won. Ojoojumo si ni Premiership n le si, ko si egbe agbaboolu to kere ni EPL bayi.

“Fun idi eyi, a gbodo ma sise kara kara ni gbogbo ipari ose. Man Utd si le gba Premiership nitori ebun Olorun po l’odo wa gan sugbon Chelsea lo l’enu lote yi.”

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ronaldo ba Raul… Arsenal ati Dortmund fi Sanogo se yeye lori twitter wipe…Mandzukic! Eyan!


Abolade Olajuwon Ryan

Real Madrid tesiwaju ninu oriire won ni Champions League, ifesewonse meje lati sa to koja, bere pelu Bayern.Atletico..Basel..Ludogorets..Liverpool ati Basel, ifesewonse meje ni won ti yege lera bayi, eleyi ko si sele siwon ri.

Latari ami ayo Ronaldo l’ano ni Madrid fi na Basel ni ami ayo kan si odo, o si ti ba Raul ninu ami ayo Champions League sugbon Messi si siwaju re. Awon mejeeji ma ma sare tele’rawon ni.

Mandzukic se bebe bi o se gba ami ayo meta wole fun Atletico bi won se na Olympiacos ni ami ayo merin si odo.

Yaya Sanogo wa gba ami ayo ikini wole fun Arsenal l’ano, nigba ti won won gbo wipe Sanogo ma bere boolu na latari ifarapa Welbeck, ni awon atileyin Dortmund ati Arsenal ba fi n se yeye ki ifesewonse na to bere. Kini won so? Awon oniroyin ‘sportsbible’ lo se akojopo yi lori twitter.

Bi won se so niyi…

– Ti Sanogo ba gba ami ayo wole, ma a bo’ra mi si ihoho ni oju ona Arbedeen.

– Ti Sanogo ba gba ami ayo wole, ma a ra aso Arsenal tuntun, aso ati sokoto, ma a si ko oruko re si leyin. Mo mo wipe ko ni gba wole jare.

– Ti Sanogo ba gba ami ayo wole, ma a je ep*n mi fun’ra mi.

– Ti Sanogo ba gba ami ayo wole, ma a kuro ni twitter.

Sanogo si doju tiwon, koda, iseju meji pere ni Sanogo fi gba ami ayo wole.

O ya Sanogo gan lenu nigba ti ami ayo na wole.

Abajade Champions League ano re e.

Atletico Madrid 4 – 0 Olympiakos
Malmo FF 0 – 2 Juventus
Basel 0 – 1 Real Madrid
PFC Ludogorets Raz 2 – 2 Liverpool
Zenit St. Petersburg 1 – 0 Benfica
Bayer Leverkusen 0 – 1 Monaco
Anderlecht 2 – 0 Galatasaray
Arsenal 2 – 0 Borussia Dortmund

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Se kini Messi yi koni se Ronaldo l’aburu bayi?


Abolade Olajuwon Ryan

Gbogbo igba ni Messi ati Ronaldo ma n so wipe ko si ija orogun laarin won, wipe egbe agbaboolu won ni awon n sa gbogbo agbara won fun, se ode l’awa ni, se awa ko mo wipe ara won gangan ni won se fun ni. Koda, ti Ronaldo ba gba bi ami ayo meta wole ni Champions League bayi, adagba ni Messi ma gba ni ojo tie lati ri wipe ohun ba Ronaldo.

Ojo ti Ronaldo ko gba ami ayo wole ni Champion League ti o fe ba iwe iranti Raul, e ri bi inu re se baje pelu wipe egbe re bori ijakadi na. To ba je egbe gangan lo n se fun, ko ni sa kuro lori papa pelu ibanuje.

Nkan gidi ti a le fa yo ninu isele yi ni wipe Messi ati Ronaldo ma n wo ira won wuwa ni, ija orogun aarin won lo fun won ni anfani lati ma dara si i lojoojumo. Ti ikan ba se daadaa loni, ikeji na ma fe se daadaa. Abajade re ni wipe fun odun mefa si meje seyin, awon mejeejo lo dara ju ni agbaye.

Barca wa fe gbe igbese kan lati je ki Barca ma gba egbe, Messi ko ni le gba ami ayo wole to bi i ti tele, nkan ti a n ro niyen sa sugbon ti o ba ri be, Messi nikan ko ni o ma se ijamba fun, Ronaldo ko ni se daadaa to nitori ko si eni ti o n ba se orogun pelu ami ayo ayafi ti Suarez to ma gba aarin ba se daadaa to.

Ese ti kika

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Adehun Messi pelu Real Madrid


Abolade Olajuwon Ryan

Bi a se n gbo wipe Messi fe kuro ni Barca, ni awon kankan ti n fi ero okan won han lati ri wipe ti awon ba ni ore ofe lati gbe Messi, awon ma suru bo ni o.

Okan ninu awon eyan yi ni akoni moogba Real Madrid Carlo Ancelotti, ohun na ti fi epo kun ina to n jo yi nipa bi Messi se fe kuro ni Barca.

“Alayo to dangajia gidi gan ni Messi” ni ‘Carletto’ so, “ti alayo ba de ti dangajia bi i Messi, ko si egbe agbaboolu ti ko ti le gba boolu. Egbe ti Messi ba darapo mo, aseyori nla ni fun won nitori o ma ran won lowo gan.

“Fun idi eyi, ti o ba seese ki adehun wa laarin Madrid ati Messi, a ma ki i kaabo ni, Messi le gba boolu fun mi” ni baba orile ede Italy na fi pari oro re.

Ese ti kika.

BBM : 28A99F82
BBM Channel: http://pin.bbm.com/C003889C7
Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.