Torres – Iru eyan ti Mourinho je simi….


Abolade Olajuwon Ryan

Leyin aadota milionu ti Chelsea san fun Liverpool lori El Nino, won ko ri owo na lara re rara.

Diego Costa ti owo re ko to ti Torres rara ti fi han wipe ohun gangan ni Chelsea nilo, nigba ti Torres ri eleyi ati wipe o dabi wipe ohun ma wa lori ijoko ni, o ya keru re lo si Italy lati darapo mo AC Milan.

Awon oniroyin wa so wipe ija sele laarin ohun ati Mou ni sugbon Torres ti tona si oro na wipe “eyan daadaa ni Mou je si mi latile ati wipe ko wu iwa buruku kan bayi si mi ir.

“Emi ni mo ba ese mi soro lati le lo si ibi ti ma ti ri boolu gba daadaa” ni Torres so fun awon oniroyin ‘Cuatro’.

“Titi di eni gan, emi ati Mourinho si ma n soro, a sin pe ara wa lori ago, o feran mi gidi gan, eyan rere ni.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Advertisements

Modric juba fun Barca


Abolade Olajuwon Ryan

Leyin ti Madrid bori Barcelona ni #elclasico alakoko sa yi, iyen to tumo si wipe ki Modric ma fun Barca ni iyi to to si won.

“Nitori a na Barca, enikeni to ba so wipe won ko lagbara, omugo ni. Barca pe gidi gan, won si ni awon alayo kabiti kabiti.

“Eni ti o ba foju di Barca, won ma fi ohu yen gbole ni.

“Ti ko ba se opelope ogbon, oye ati agbara ni, a ko ni na won o. Abi to ba je wipe Messi gba ami re wole ni, o ma nira fun wa lojo satide yen.

“E ma foju di Barca o” ni ikilo Modric.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Tevez se oriire fun ija to ma ko si Ronaldo ati Modric


Abolade Olajuwon Ryan

Nigba ti Martino gba ise Argentina, o so wipe gbogbo alayo to ba se daadaa fun egbe won lo ma ni anfani lati darapo mo egbe ti re.

Lowo lowo yi, erujeje ni Tevez je ni Juventus, ami ayo mejo ninu ifesewonse mewa, ise nla ni, Martino si ti mu ileri re se lati pe pada si egbe Argentina.

Odun 2011 ni Tevez gba boolu fun Argentina gbeyin sugbon o ma wa lara awon to ma koju ija si Modric ati Ronaldo nipa ti Crotia ati Portugal ninu ifesewonse ore si ore.

Willy Caballero na, amule Man City na yofa bi o ti le je wipe ko gba boolu daadaa to fun Man City.

Gbogbo alayo ti Martino pe leyi –

Sergio Romero (Sampdoria), Willy Caballero
(Manchester City), Nahuel Guzman (Tigres)

Nicolas Otamendi (Valencia), Martin Demichelis
(Manchester City), Marcos Rojo (Manchester United), Pablo Zabaleta
(Manchester City), Federico Fazio (Tottenham), Federico Fernandez
(Swansea), Ezequiel Garay (Zenit), Facundo Roncaglia (Genoa),
Cristian Ansaldi (Atletico Madrid)

Javier Mascherano (Barcelona), Ever Banega (Sevilla),
Robert Pareyra (Juventus), Lucas Biglia (Lazio), Angel Di Maria
(Manchester United), Erik Lamela (Tottenham), Javier Pastore (Paris
Saint-Germain), Enzo Perez (Benfica), Nicolas Gaitan (Benfica)

Lionel Messi (Barcelona), Carlos Tevez (Juventus),
Gonzalo Higuain (Napoli), Sergio Aguero (Manchester City).

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

FIFA – Ebun ta fun Messi ko….


Abolade Olajuwon Ryan

Lati igba yi titi de osu kini odun to n bo, oro FIFA la ma ma gbo ju nitori Ballon d’Or.

Awon alayo na ma fe se dara dara lati ri wipe awon ni o ma gba ebun won.

Ni World Cup, a fun Messi ni boolu wura, iyen ami eye fun alayo se daadaa ju ni World Cup, gbogbo eyan lo so wipe ife eye yen ko to si rara, Maradona gan so be, wipe won ko fe fi Messi polowo ni.

Awon FIFA to fun Messi ni ife eye na ti gba enu aare won soro wipe “asise nla la se lati fun Messi ni ife eye na, nitori ko to si rara, Neuer, amule Germany ni ife eye na to si” ni Blatter so.

“Awon arindi ta fi si idi ife na so wipe alayo mewa nikan lawon foju si lara to gba asikagba World Cup na.”

A be tie ma gboro, se nkan ti won ba so ko ni won ma se ni, ki won da wa un jare!

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Bacca na Di Maria ati Neymar


Abolade Olajuwon Ryan

Won ti se ayeye LFP fun awon alayo to dangajia ju lo ni La Liga.

Lara awon egbe ti won fe fun ni ebun ni alayo to dangajia ju to wa lati South America.

Neymar, Di Maria ati Carlos Bacca ni won yan lati ja fun ife eye na sugbon alayo Sevilla na lo gba ife eye na, Carlos Bacca.

Yacine Brahimi, omo orile ede Algeria to wa ni Porto lo gba ami eye fun alawo dudu to dangajia ju ni Spain ni sa go koja. Granada lo wa ni sa to koja.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Kilo fa ija Ancelotti, Mourinho, Guardiola ati Van Gaal?


Abolade Olajuwon Ryan

Akoni moogba Bayern Munich to gba ife eye meta ni odun 2013, Heynckes lo gba ife eye Ballon d’Or fun awon akoni moogba ti odun to koja.

Tani o ma gba ti odun yi? Se Ancelotti to gba Champions League ni tabi Joachim Low, akoni moogba Germany to gba World Cup, tabi Van Gaal to ba Holland gbe ipo keta ni World Cup layi padanu ifesewonse kankan tabi Mourinho ti ko gba nkankan rara, tabi Diego Simeone to gba agbara lowo Madrid ati Barca lati gba La Liga lowo won fun Atleti, tabi Guardiola to gba ife eye marun pelu Bayern Munich?

Ojo kejila osu kini odun to n bo la ma mo…….

Awon ti won mu fun ife eye na re e –

Carlo Ancelotti (Italy/Real Madrid CF), Antonio Conte (Italy/Juventus
FC/Italy national team), Pep Guardiola (Spain/FC Bayern Munich),
Jürgen Klinsmann (Germany/ USA national team), Joachim Löw
(Germany/Germany national team), José Mourinho (Portugal/Chelsea
FC), Manuel Pellegrini (Chile/Manchester City FC), Alejandro Sabella
(Argentina/Argentina national team), Diego Simeone (Argentina/
Atlético Madrid), Louis van Gaal (Netherlands/Netherlands national
team/Manchester United FC).

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Modric – Lowo yi o, mi ko ti i ri iyalaya en…


Abolade Olajuwon Ryan

Lowo ti Madrid na Barcelona bayi, won ti n buga ni o, won gara tan ni o.

Awon oniroyin ‘Sportske Novoski’ ni Modric ba soro wipe “bayi bayi, a ti so fun araye iru agbara to kun si Madrid lowo.

“T’aba n gba boolu lo bayi, mi ko i ti fi iyalaya egbe agbabolu na ti ko ni je iya lowo wa. A ko bere boolu dada ni ojo na sugbon leyin bi ogun iseju, a di egungun eja mowo lowo ni.

‘Lati igba ti mo ti de Madrid, a ko gba boolu daadaa to ojo yen.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Real Madrid tun fi iya je Barca bayi o


Abolade Olajuwon Ryan

Iranu ti Barcelona se ni sa to koja ti yole bayi o, alayo won kan pere lo wa ninu awon alayo go gba ami eye LFP ni Spain, iyen Iniesta.

Awon alayo Barca ti won tu gba ami eye je awon tiwon sese ra lati egbe omiran, Rakitic ati Rafinha ti won ya Celta ni sa to koja.

Real Madrid, alayo won kan soso gba ife eye meta, e sa ti mo eni ti mo n so, CR7. O gba ami eye fun alayo to dangajia ju lo, eni ti ami ayo re dun ju ati ife eye alayo to n gba iwaju ju.

Ramos ti Madrid na gba ami eye alayo to n gba eyin ju, Modric wa gba ami eye alayo to n gba aarin.

Amule Madrid ti won ra lati Levante lo gba amule to dangajia ju fun sa to koja.

Atletico to gba ife eye La Liga gan, ami eye kan soso ni won ri gba, akoni moogba won si lo gba, Diego Simeone.

Barca na ti je igbadun bayi seyin sugbon ki won ya mufa sise o.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ha! O ma se o! Zinedine Zidane…. ki lo de na?


Abolade Olajuwon Ryan

Lati bi osu meta seyin lati n gbo wipe awon adari boolu Spain fe fi iya je ‘Zizou’ nitori iwe lati dari Real Madrid Castilla ko pe, ese nla si ni.

Nigba ti won koko lo si ile ejo, Zizou so wipe looto ni wipe iwe ohun ko pe sugbon ohun ko ni akoni moogba Castilla, wipe igbakeji lohun je ati wipe awon to n tako ohun ko n jowu ni.

Zidane ni iwe UEFA A sugbon o ku badge 3 lati ri wipe iwe re pe, Zidane ko si ni i.

Osu meta bayi ni adajo Francisco Rubio ni ki Zidane fi joko si ile fe fun ese yi sugbon Real Madrid ti tako idajo na nitori si won o, iwe re pe nitori o ye ki Zidane lo si Bordeaux gan tele ni ti Madrid ko ba be e ko duro.

Zidane so fun awon oniroyin ‘La Figaro’ wipe “emi ko da ese kankan o, egbe Real Madrid mi wa leyin mi bi ike ni, awon olote to n wa ijakule mi na, oju won a ja.”

Ojo mewa ni Zidane le lo fi bebe nile ejo o.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Yeepa! Germany 6 – 0 England


Abolade Olajuwon Ryan

Michel Platini, aare UEFA, so wipe alayo orile ede Germany ni o gbodo gba ami eye Ballon d’Or ti odun 2014 (fun alayo to dangajia ju lo ni odun 2014) nitori World Cup ti won gba.

Awon ajo FIFA ti gbe iwe oruko awon alayo na sita, alayo metalelogun lo wa nibe, omo orile ede Germany mefa si ni o wa ni ibe, ko si si omo orile ede England kankan nibe.

Ojo kejila osu kini odun 2015 ni won ma se ayeye na ni Zurich leyin ti awon akoni moogba ati ogagun orile ede ba dibo fun alayo ti ife eye na to si.

Gbogbo awon alayo ti won wa ninu iwe oruko na re o.

Gareth Bale (Wales), Karim Benzema (France), Diego Costa (Spain),
Thibaut Courtois (Belgium), Cristiano Ronaldo (Portugal), Angel Di
María (Argentina), Mario Götze (Germany), Eden Hazard (Belgium),
Zlatan Ibrahimovic (Sweden), Andrés Iniesta (Spain), Toni Kroos
(Germany), Philipp Lahm (Germany), Javier Mascherano (Argentina),
Lionel Messi (Argentina), Thomas Müller (Germany), Manuel Neuer
(Germany), Neymar (Brazil), Paul Pogba (France), Sergio Ramos
(Spain), Arjen Robben (Netherlands), James Rodríguez (Colombia),
Bastian Schweinsteiger (Germany), Yaya Touré (Côte d’Ivoire).

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.