Beyonce, Jay Z ati Beckham ba PSG na Barcelona


Abolade Olajuwon Ryan

Awon to gbe owo le Barca je gbese!

Cavani so awon ami ayo nu la’poju. Iba je wipe Ibrahimovic gba boolu loni ni, iya Barcelona ko ba po ju bayi lo.

Barcelona ko’i ti padanu ifesewonse kankan ni sa yi, koda, ko si egbe agbaboolu kankan to gba ami ayo wole s’odo won.

Ter Stergen, amule Barca, ifesewonse akoko re re o ti o ti je ami ayo meta, eleyi ti ko sele si Bravo ni ifesewonse mefa tie.

Jay Z ati iyawo re Beyonce wa lori ijoko ni Paris lati fikun igbadun won, won fi yen wo boolu Barca. Agbaboolu PSG tele tele na Beckham wa lori ijoko. Boya eyi lo fun PSG ni itara lati bori Barca.

Ami ayo meta si meji ni PSG na Barca.

Chelsea na se bebe latari wipe won na Sporting Lisbon. Eleyi ko sele ri wipe egbe agbaboolu na Sporting mole ni Champions League fun bi ifesewonse merindinlogun seyin.

Awon abajade Champions League toni re o.

CSKA Moscow 0 – 1 Bayern Munich
Manchester City 1 – 1 Roma
APOEL Nicosia 1 – 1 Ajax
Paris Saint Germain 3 – 2 Barcelona
Schalke 04 1 – 1 Maribor
Sporting CP 0 – 1 Chelsea
BATE Borisov 2 – 1 Athletic Bilbao
Shakhtar Donetsk 2 – 2 FC Porto

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Advertisements

Carlos – Oganla ni Ancelotti ati Casillas fun awon idi wonyi


Abolade Olajuwon Ryan

Odun mokanla ni Casillas ati Roberto Carlos fi gba boolu papo ni Madrid, o mo Iker daadaa.

Awon atileyin Real Madrid ti n kigbe wipe ki Casillas ma dile mu mo o, wipe Keylor Navas ni awon fe bayi.

“Odun marundinlogun bayi ni Casillas ti wo aso Real Madrid, ko si nkan to buru ju ninu bi won se fe ki o se daadaa si sugbon o ye ki won bowo fun.

“Egbagbe Alonso ati Di Maria to lo, mo bowo fun Ancelotti, o sise daadaa ni sa to koja, o si ma se ju be lo. Koda, Madrid le gba Champions League ikankanla.

“Marcelo to n gba ipo mi ni Madrid n se ise re daadaa, sasa ni eni ti o n gba ipo re julo ni agbaye.”

Carlos lo se gbogbo eleyi, Se otito ni?

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Mourinho tu asiri Diego Costa


Abolade Olajuwon Ryan

Mourinho so tele wipe Diego Costa ko le gba ju ifesewonse kan soso ni ose kan nitori isan re to ni ifarapa.

Bayi bayi, eni ti o ye ki o dipo re ni Didier Drogba sugbon Drogba na ti ni ipalara. Kini Mou ma se bayi o fun Champions League?

O ni ohun ma lo Costa be ni! Pelu ipalara re ni o.

“Sugbon o, ki enikeni ma gbojule Costa o nitori ko gbaradi o, o kan simi ni sa, ko gbaradi gan.

“Sibe sibe, o ma koju ija si Arsenal gan ni ojo sonde.”

Mou so wipe Drogba ko ba won rin irin ajo pelu won lo si Portugal fun Champions League ti won fe koju ija si Sporting, Drogba si ma wa nile fun igba die.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Lionel Messi – Oganla Esin


Abolade Olajuwon Ryan

Messi dara gan o, e gbagbe wipe won fi ohun ati Ronaldo we ara won, awon mejeeji je alayo to dangajia ni aye arawon.

Lionel Messi, pelu ami ayo meji ti o gba wole si odo Granada ni ano, o ti gba ami ayo ogorun merin le ni eyo kan wole ni igbesi aye boolu re.

Ninu re, mejilelogoji ni o gba wole pelu Argentina ti iyi toku je ti Barcelona.

‘Mi’o lero re ri wipe mo ma gba ami ayo ogorun merin wole ni igbse aye boolu mi” ni Messi ko sori facebook re.

Messi wa dupe lowo awon egbe re ni Barcelona ati Argentina wipe awon lo je ki o rorun fun, wipe ohun de ma tiraka lati se daadaa si.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Gbese Manchester United lori Ronaldo


Abolade Olajuwon Ryan

Ronaldo gangan ti soro nipa ipadabo re si Man Utd.

Man Utd ti ko lo si Champions League ko won si gbese gan latari awon owo to ye ki won gba.

Iye ti Man Utd ti na ni saa yi lori rira alayo ti le ne igba milionu, wipe won tu fe ra Ronaldo yen, gbese nla ni.

Real Madrid si ti so fun CR7 wipe ki o ma ro rara nitori Madrid lo ma pari igbesi aye boolu re si.

Owo ti Ronaldo n gba ju ogun milionu ni odun kan, Man Utd lagbara ati san o sugbon gbese ni fun won, agaga ti won koba lo si Champions League.

Idi ti Ronaldo gangan ko fi ni lo si Man Utd ni wipe Man Utd ti paro aladire won lati Nike si Adidas. Bata ti Ronaldo si n je Nike.

Ti Man Utd ko ba tu lo si Champions League peren, ogorun milionu lodun ma din ku si ogota milionu.

Ronaldo fe gba Champions League, ko si le lo si egbe ti ko ni gba boolu nibe.

“Oro rada rada ni won so o, inu mi dun ni Madrid, ibe ni ojo iwaju mi wa” ni Ronaldo so bayi.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Zlatan – didirin ni Guardiola nitori….


Abolade Olajuwon Ryan

Ibrahimovic, alayo PSG to ma koju ija si egbe re tele Barcelona, ti gba boolu fun egbe agbaboolu Inter, AC Milan ati Barcelona, awon egbe yi ti gba ife eye yi sugbon Ibrahimovic ko ti gba ife eye yi ri.

Zlatan ti wa n da akoni moogba re ni igba to wa ni Barcelona lebi wipe ohun lo se okunfa aimagba ife eye na igbana.

“Isesi ko wa ni eko nigba yen lo se okunfa aima gba ife eye yi ni 2010, eko didirin Guardiola ni Inter fi na wa.

“Mi ti gbagba re sa, Barcelona ni egbe to dara ju ni igba yen, mo si gbadun ara mi nibe’ ni Ibrahimovic so fun awon oniroyin Canal+.

“PSG ni anfani ti mo ni lati gba Champions League, a si fe koja ibi t’ade ni sa meji seyin”.

Sugbon boolu ti ose yi o, Zlatan ko ni gba boolu pelu Barca.

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Raheem Sterling ni Real Madrid


Abolade Olajuwon Ryan

Ti alayo ba se daradara gan, ko si iye ti Real Madrid ko ni ko sile lati fi ra a.

Sportsinyoruba so fun yi tele wipe Raheem Sterling ni Madrid fe fi dipo Di Maria ti won ba ta a sugbon James Rodriguez ni won wa ra.

Real Madrid nikan ko ni won fe ra ogbeni omo odun mokandinlogun na sugbon eleyi ko ba akoni moogba re leru nitori o mo wipe ko ni kuro ni Liverpool. Bo tie ma lo, ki i se isin.

“Awon ti won fe ra Sterling po gan sugbon okan mi bale lori oro na.

“Omo nla ni Sterling, o sise de ibi ti o wa yi ni” ni Rodgers so.

“Suarez ti o kuro ni odo wa fi wa die, o si je dandan ki o ri be. A ma la asiko yi ja.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ija Arsene Wenger ati Lampard


Abolade Olajuwon Ryan

Inu Arsene Wenger, akoni moogba Arsenal ko dun mo ona ti Man City gbe gba lati fa Lampard si odo won.

Lampard kuro ni Chelsea leyin odun metala re nibe, o darapo mo New York City ni America. Man City na ni o ni egbe agbaboolu yen, won wa fi anfani yen fa Lampard si Man City nitori boolu ko’i ti bere ni America nigba na.

Inu Arsene Wenger ko dun si eyi, o lero wipe “ona yi ko fibe boju mu lodo mi.

“O dabi wipe Lampard moomo lo si America lati le wa si Man City ni, o le je nitori wipe o fe gba boolu pelu awon agbaagba, Chelsea ko si fun ni anfani yi mo.”

Arsene Wenger wa so wipe ona agabagebe yi le ti owo Man City wa latari wipe “o tu le je wipe won fi Man City lo Lampard, o si wo o loju.

“Lampard gangan ni o le salaye oro yi bi o se je gan.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Ipadabo Ibrahimovic si Barcelona


Abolade Olajuwon Ryan

Champions League tu wole de bayi, Barcelona ati PSG ni won ma koju ija sira.

Esin nla PSG, Ibrahimovic ti o gba boolu fun Barcelona lati odun 2009-2011 ni ipalara pelu Thiago Silva ati Lavezzi.

Akoni moogba re Laurent Blanc ti pinu lati ma lo pelu Bordeaux, ki atele ese re to ti sese le fi jina daadaa ti won ba koju ija ti Barcelona.

“A si nilo lati wo Ibrahimovic fun ojo meji si ki a to le mo boya o ma le gba boolu pelu Barcelona. Ti ko ba si gbaradi to, Cavani ma se ise re daadaa.

“Ara Thiago Silva ko’i ti ya rara sugbon o seese ki ohun na gba boolu pelu Barcelona.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.

Suarez di orobo o!


Abolade Olajuwon Ryan

Ami ayo meji ni Suarez gba wole nigba ti o ba awon omode Barca koju ija si ti Indonesia. Ami ayo mefa si odo ni Barca si na won ni ojo na.

Pelu bi o se gba boolu ni ojo yen, o da bi wipe o ti tobi si i ati wipe o tete re e.

Akoni moogba re Luis Enrique ti da ina bo oro na wipe “orobo ke, laye laye. Ko jo rara! Bi o se ri ni Liverpool na ni o se ri.

“Oro yama yama awon oniroyin niyen jare. Inu mi dun pelu bi o se ri gan ni.

“Suarez lagbara gan, o ko lara ni.”

Ese ti kika.

Fun ipolowo ofe, e le kan siwa ni
sportsinyoruba@gmail.com.
iwe iroyin wa n bo layipe.
E jowo, e ma gbagbe lati feran wa lori http://
http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati
http://www.twitter.com/sportsinyoruba.