Eranko ni Pepe pe mi – Keita

Abolade Olajuwon Ryan

Ki lo ma n se awon agbaya meji yi na? Eyan dudu meji ti ikan tu n pe ikan ni obo, sago n bugo.

Oro odun melo kan seyin mani, nigba ti Keita wa ni Barca, ni ohun ati Pepe Madrid fe ja, ni Pepe ba pe ni obo.

Oro bi odun melo kan seyin ni o, ni Madrid ba pade Roma ni America. Ase Keita to wa ni Roma nisin ko gbagbe oro ojosi, ni ko ba gba Pepe lowo, ni Pepe ba tu ito si loju, yeepa!

Gobe ba sele, ni Keita ba ju igo omi lu Pepe, sugbon Pepe so wipe “obi, ko ba mi”.

Leyin ifesewonse na ni Keita wa jewo wipe “mi ko fe so fun awon oniroyin ni, sugbon ati igba ti Pepe pemi ni obo, ko je nkankan loju mi mo.

“O ye ki o bere idi ti mi ko se gba lowo, sugbon o tu wa tu ito simi loju” ni Keita so.

“Mi ko loro ba so o, nitori mi ko je eyan niwaju re. Sugbon Keita fi ejo sun Alonso ati Ramos.

Awon eleyi n di oro sinu o, twale o!

O ye ki Pepe toro aforiji o.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Advertisements

Man Utd gbodo ni suru – Van Gaal

Abolade Olajuwon Ryan

Akoni moogba Man Utd, Luis Van Gaal ti kilo fun awon atileyin Man Utd wipe ki won ma ro boya ni kiakia ni iyanu ma sele o sugbon iyanu ma sele leyin osu meta.

“Ni gbogbo egbe agbaboolu ti mo ti ko, mo man ni isoro ni osu meta akoko.

“Idi ni wipe isesi mi ko n tete mo won lara” ni Van Gaal so ni America.

O tu wa ni “mo feran ki awon alayo mi ma lo ogbon won ju ese lo, ki won mo idi ti won se fe se nkan ki won to se e.

“Sugbon o, ti iwa wa bati bara mu, a ma yege gan ni o” ni Van Gaal so.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Dunga tasi David Luiz, Neymar ati Alves

Akoni moogba Brazil tuntun Dunga, gbogbo eyan lo mo o si eni ti ko ran eyan kankan nise, o ma so tire sa ni.

Bayi bayi, o ti soro si bi awon alayo Brazil se wu iwa ni World Cup.

O bere pelu Luiz ati awon alayo to sun ekun nigba ti won ba Chile gba boolu ati ti o sukun nigba ti Germany na won.

“Alagbara niwa, isan wa le gan, a kin se obirin, a ko le sun ekun rara mo o.

O wa ba awon idile sango na soro. O ni ki Neymar ati Alvez ti won paro irun da, ti won da oda sori bi akunle ko gbodo sele mo, o ni ti won ba fe se irun kankan, ki won se ki idije to bere sugbon ki idije bere tan, ki won sese wa ma tun iru se yen, ko gbodo sele mo o.

O wa ni ki enikeni ma wa kiri oja o. Neymar lo n ba soro yen. O ni ti ohun ba mu alayo kankan lo si odo awon oniroyin, ko gbodo wo fila kankan yato si fila Brazil o, ko gbodo ba eyan kankan polongo oja re.

Oga yi le o, a si ma ri iyipada.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Everton ti ra Lukaku

Abolade Olajuwon Ryan

“Inu mi dun lati pada si Everton, emi ati akoni moogba wa Martinez mo owo arawa gan ni” ni oro to jade lenu Lukaku ti Everton san iru owo ti won ko san ri fun alayo, milionu marundinlogoji.

Everton ni Lukaku gba boolu fun ni sa to koja, Juventus na si fe ra ogbeni na sugbon o wu lati pada si Everton ni.

“Bi n pe kati bere sa yi lo ri fun mi, ki a bere si ni fo gbogbo eyan lenu.

“A mo wipe Lukaku kere gan sugbon, ebun Olorun wa lowo re gan, o si wu awa lati to dagba gan” ni awon ti Everton so.

Lukaku ti Chelsea fe fi dipo Drogba ni Drogba dipo bayi o.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Ronaldo lo pe ju laye yi

Abolade Olajuwon Ryan.

Oro laarin Messi ati Ronaldo la tu gbe de yi o, nipa tani o pe ju. Messi ko le se gbogbo nkan, sugbon Ronaldo le se gbogbo nkan ni boolu ni Owen so.

“Ni gbogbo aye yi o, emi na je alayo to pe gan sugbon eni ti o pe ju ni Cristiano Ronaldo” ni Owen so nigba ti Ronaldo gba ife Goal 50.

“O n ge ege, o mo ere sa, o mo ami ayo gba wole, o mo ori lo, ebun olorun pe si lara, ejo, Ronaldo ni.

Owen wa pari oro re bayi wipe “e le gbekele Ronaldo ninu ifesewonse.

Se ooto lo so?

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Sabella fi ise akoni moogba Argentina le

Abolade Olajuwon Ryan

Akoni moogba ti o gbe Argentina wo final World Cup lati bi odun meedogun ti fi ise na sile.

Sabella ti so eleyi ki Germany tie to na won.

Awon ajo boolu ni orile ede Argentina ni won fi oro yi to wa leti.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Ara Iheanacho bale – Inzaghi

Abolade Olajuwon Ryan.

Lotun losi ni okiki Iheanacho ti n kari agbaye o.

Nigba ti o fe lo si Man City, awon omo Nigeria bere sini pariwo, ha! Ye! Koma lo o! Ko ni ri aso gba nibe!

Bayi bayi, ati akoni moogba Man City o, ti AC Milan o, awon oniroyin agbaye o, gbogbo ni won bu epo si ina ori re.

Iheanacho ti gba ami ayo meji wole bayi ninu ifesewonse meji ni akoni moogba AC Milan ti won na ni ayo marun si okan, Felipe Inzaghi se so wipe “ara omode yen bale gidi gan, ko n beru niwaju amule rara, ti o ba farabale, ojo iwaju re dara.

Iheanacho ti ko ti pe omo odun mejidinlogun ko ni le ba Man City bere sa yi nitori ni England, ajoji gbodo pe omo odun mejidinlogun ko to le bere ise.

Pellegrini na so wipe “Iheanacho ti se gbogbo nkan ti o le mu wo egbe awon agba Man City.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Roma le Madrid kuro ninu idije International Cup

Abolade Olajuwon Ryan

Guiness Cup to n sele lowo lowo ni America ni AS Roma ti ko egba bo Real Madrid ni aaro yi.

Ayo kan lati owo Totti si odo ni won na Madrid.

Iko kiini ni Madrid ti se daadaa jare, won ko fibe fun ara won laye ati gba ami ayo wole ni iko keji.

Enikeji ti o ma na Madrid to gba ife eye na bi sa to koja re, Inter ti koko na Madrid tele ni ayo meta si meji.

Man Utd ni tiwon na Inter Milan ni Penalty pelu ayo marun si meta.

Madrid ati Man Utd lo ma pade bayi.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Griezmann ki Real Sociedad odabo bi o se n lo si Atletico

Abolade Olajuwon Ryan.

Alayo tuntun ti Atletico ra bayi, Antoine Griezmann, omo orile ede France ti ki egbe re tele, Real Sociedad wipe o di gbere o.

“Omode ni mo je nigba ti mo wa si ibi yi, okurin lanti lanti ni mi bayi bi mo se n lo.

O lo ki awon ore re ni ori papa igbaradi ki o to so wipe “omo odun metala nimi nigba ti mo wa, mo si ti lo odun mewa nibi.

“Inu mi dun pelu igbesi aye ati ise mi ni Real Sociedad, o di gba o.

Atletico Madrid ni Griezmann darapo mo, akoni moogba Atleti si ti so wipe “Griezmann ma je ki a dara ju bi a se wa lo tele.

Ese ti kika.

E jowo, ema gbagbe lati feran wa lori http://www.facebook.com/sportsinyoruba ati http://www.twitter.com/sportsinyoruba. Fun ipolowo, imoran tabi isina, e le kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com. e ku ife.

Ewo nkan ti won gbe si Neymar leyin

Leyin ti Zuniga fi orukun kan egungun eyin Neymar, o ti lo sinmi ni Ibiza, lorile ede Spain ki o to darapo mo awon egbe re toku fun igbaradi sa tuntun.

Ewo iku re nini aworan yi, won so nkan mo ikun, Neymar lo wa ni aarin awon meji yi oko oju omi.

Ipalara yen lewu gan o.