Suarez toro aforiji lowo Chillini ati agbaye

“Mi o moomo ge Chiellini je o, orukun mi ni o ye ti mo fi wa ko lu” ni Suarez so tele.

Bayi bayi, o ti gba wipe nkan ti ohun se ko dara, o so wipe iru re koni sele mo, ibanuje aye ati orun ni o je fun ohun.

Itori aforiji mi re e

“Nigba ti mo de ile, leyin arojinle gidi, mo ro isele emi pelu Chiellini, mo si ri wipe nkan ti o sele ko boju mu.

Nitori idi eyi, Suarez so oro pataki meta

– Ibanuje ni isele yi je fun mi.

– Mo toro idariji lowo Chiellini ati gbogbo oni boolu ni agbaye.

– Mo se ileri wipe iru isele yi ko ni ti owo mi waye mo laye laye.”

O da bi o se jewo bayi.

Abolade Olajuwon Ryan.

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Advertisements

Suarez so wipe eyin si n dun ohun.

Luis ti FIFA fi esan kan wipe o ge Chiellini je ti ro ejo tire, oso wipe ohun ko ge Chiellini je o.

FIFA so wipe nkan ti ijiya re se po to beyen ni wipe Suarez ko bebe rara, iyen tu mo si wipe o moomo ge Chiellini je ni FIFA so.

“O moomo fe se Chiellini lese ni nitori ko si boolu ni ese awon mejeeji ki o to ti eyin bo leyin” ni FIFA so.

Hmmm! Bi Suarez se so oro tire niyi “nigba ti mo. Wa ni egbe re, orukun mi ye ma ni, mi ko si le duro daadaa mo, nkan ti o mu mi subu le Chiellini beyen niyen, igbayen ni enu mi ba.”

“Mo sese ni eke mi gan, eyin mi sin dun mi titi di isin, mi ko ni lokan lati ge enikeni je, mi ko si ge je rara ni.”

Ta ni a ma gbagbo bayi?

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Isoro mi ni Barca – Martino

Tata Martino ti o je akoni moogba Barca ni sa ti o koja ti so idi ti ohun se kuro ni Barca.

O so wipe ati se orire ni Barca rorun, sugbon ati ma se orire lo titi ni koseese ni ibikibi.

O so wipe inu ohun dun bi awon alayo re se ma n so oro ohun nita gbangba sugbon ise na su ohun nitori “ni Barcelona, ti a ba jawe olubori kankan, awon alayo mi won ma ki ku orire.

Iyen ko ti e dun Martino rara, nkan ti o wa dun Tata ni wipe “ti won ba file na wa bayi, emi ni mo ma n fi ori ko. Nkan ti o je isoro mi ni Barca niyen.

Buenos Aires ni ohun ati Pep Guardiola ti ba awon oniroyin soro wonyi.

O si tu so wipe “nigba ti Pep wa ni Barca ni Barca dara ju, ko si igba ti o dara ju igba Pep lo.

Abolade Olajuwon Ryan.

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Greece gba World Cup layi gba kobo.

Nibi ti awon alayo Nigeria ko lati gbaradi fun ifesewonse won pelu France, awon alayo Greece se bebe.

O da bi wipe awon alayo Greece ko feran ibi ti won ti ma n gbaradi fun idije nitori igba ti won fe fun won ni owo kun owo idije World Cup won, awon alayo na ni “idunu wa ni lati gba boolu fun orile ede Greece. Awa ko nilo owo ile.”

“Ejowo, e ba wa fi owo ti e fe fun wa ko ile ati papa to dangajia, ki awon alayo ojo iwaju Greece le ni alafia nigba ti won ba fe se igbaradi fun idije kankan.

Iwa yi dara gan nitori won ko fi owo siwaju ise won.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Barca san owo die fun Suarez

Bi Suarez se bu Chiellini je ni World Cup, o je ki Suarez run si Real Madrid.

Real Madrid je egbe ti ko gba igbakugba fun awon alayo re, won gbodo wu iwa daadaa.

Nitori re ni ona se si fun Barca lati ra Suarez. Suarez na si ti so fun Bartomeu, aare Barca wipe o wu ohun lati wa si Barca.

Milionu aadorun ni Barca fe san le bayi, sugbon won fe fi Tello, Pedro tabi Song kun adehun na ki owo re le din ku.

Owo ti Suarez si n gba ni Liverpool je milionu mewa pon ni odun. Eleyi ko soro fun Barca.

Oro Chiellini na dun Barca sugbon won si fe tesiwaju. Real Madrid ko Suarez sile ni bamu bamu.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Liverpool gbodo duro ti Suarez

Leyin ijiya ti FIFA fun Suarez, akoni moogba Liverpool tele ti o ra Suarez wa Liverpool so bi ohun se ro bi Liverpool se ma se.

“Gbogbo eyan ni o le so ohun ti o wu won nipa Suarez tabi nkan ti Liverpool ma se, sugbon nitori ese Suarez, iyen ko tumo si wipe Liverpool ma da a nu. Won gbodo duro ti ni.”

Dalgish tu so wipe ijiya re ko je ki o kan egbe agbaboolu re Liverpool nitori “nigba ti Suarez se ni England -ti o ge Ivanovic je-, FA so wipe ko ni gba boolu fun Liverpool fun bi osu meji sugbon won ko da duro lati gba boolu fun Uruguay. Uruguay si ni Suarez ti se, ijiya re ko ye ki o kan boolu re fun Liverpool.”

Suarez ko ni ba Liverpool gba boolu titi di osu kankanla odun ti a wa yi.

Pelu gbogbo re na, o ni Liverpool ma duro ti Suarez ni.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Cannavaro dipo Zidane ni Madrid

Bi Zinedine Zidane se di akoni moogba Real Madrid B, aye igbakeji Ancelotti to si le.

Ancelotti ko si rin jina, alayo re ti won jo sise papo ni Parma lati odun 1996 de 1998 Fabio Cannavaro ni o fe fi dipo re bayi.

Ancelotti ni “o ti lo odun meta nibi, awon alayo ati atileyin Real Madrid feran re gan.

“O ni iriri to daju, iwe re pe, ohun ni ipo Zidane ye.

Nigba ti Cannavaro gba Ballon d’Or ni o darapo mo Madrid ni 2006, o si gba ‘La Liga’ meji.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Man Utd ati Arsenal ja lori Alexis

Gbogbo sa ni a ma n gbo wipe Alexis ma kuro ni Barca.

Lowo lowo bayi, awon oniroyin ‘Daily Mail’ ti fi ye wa wipe Arsenal ati Man Utd ni won fe ra .

Milionu ogbon ni won setan lati ko sile.

Alexis n se daadaa ni Brazil pelu orile ede re Chile, o si n se daadaa fun Barca na pelu.

Ti o ba ma lo si ibikibi, o le ma je Man Utd, nitori won ko ni gba Champions League ni sa yi.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

David Villa ko gba boolu fun Spain mo

David Villa, El Guaje, alayo Atletico Madrid ti feyin fun boolu orile ede.

O se eyi lati yo eru ati ise to wuwo ni ori re, ki o le koju mo boolu egbe re.

Sugbon o, o fi eyin ti pelu aseyori nla ni.

Ko si alayo ti o gba omi ayo wole ju Villa lo, omi ayo mokandinlogofa ni o gba wole, ikehin ni eyi ti o gba wole nigba ti won koju ija ti Australia.

Leyin ifesewonse na, o n sun ekun ni, ti De Gea, Casillas ati Pique n tu lara.

Diego Costa gan ko gba omi ayo kankan wole ni World Cup yi

Odun mesan ni o fi gba boolu fun Spain, World Cup meta ti o gba pelu Spain, o gba omi ayo wole ni gbogbo re.

Omo odun mejilelogbon ni Villa, Melbourne City ni Australia ati Newyork City ni America ni won fe ra Villa bayi.

“Nipa ojo ori mi ati bi ara mi se ri bayi, asiko ti to lati feyin ti” ni El Guaje fi se afeyinti re.

Oseese ki Casillas, Alonso ati Xavi na feyinti pelu re.

Abolade Olajuwon Ryan.

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @ http://www.facebook.com/sportsinyoruba. e si le tele wa lori twitter lati http://www.twitter.com/sportsinyoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Brazil fe gba boolu bi Atletico Madrid – Scolari

Scolari, akoni moogba Brazil ti so bi Brazil se ma gba boolu ti won ba koju ija ti Chile ni ojo oni.

“Owo Atletico Madrid ni a ti ma ko eko bi a se ma ba Chile gba boolu. Atletico ni eto, won mo bi won se ma n di ile mu, won si le tete suru bo yin ti e ba lo go ara yin. Iru boolu ti a fe gba niyen” ni Filepe Scolari ti o ba Brazil gba World Cup ni 2002 so.

O tu fi ye wa wipe ohun ti mo awon ti won ma bere boolu na ni eni sugbon ohun ko fe daruko won, ki o ma da ija le laarin awon alayo re.

Sugbon o, eni ti o seese ki o paro ni Dani Alves fun Maicon, alayo Roma.