E jeki awon alayo ba obirin sun daada ni World Cup.


“Ni igba ti awa n gba World Cup, ti o ba je wipe akoni moogba wa ba je ki a ni ajosepo pelu obirin ni, ko ba dara, ibasepo yi ma je ki okan wa bale ninu awon ifese won ese wa.

Valderrama, agbaagba boolu afesegba ti orile ede Colombia lo so be.

Akoni moogba Mexico ati ti Brazil ti so fun awon alayo won wipe, awon ko gbodo riwon pelu obirin kankan, titi idije World Cup ma fi pari.

Ki alayo ma ba obirin sun ju, ko ma dara fun ise boolu gbigba, sugbon awon baba yi ko lero re beyen ke.

“Mi o so wipe ki ibasepo na je ti alagidi o, die die ni, iyen ni o ma je ki awon alayo naa ni ifokanbale ninu awon ifese won ese won.

Ohun ti a gbo lati enu Valderrama niyen o.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Advertisements

Mourinho fe ta Peter Cech fun Courtois


Gbogbo eniyan ni o mo Mourinho si baba ti ko ran eyan ni ise rara, nkan ti o ba wu lokan ni o ma se e.

Casillas ti o je babanla amule ni Spain, nigbati ise re ko te Mourinho lorun, o gbe joko ni.

Mata ti o siwaju Chelsea fun odidi sa meji, ko te Mourinho lorun, o ta danu.

David Luiz nko, o ti fe ta danu.

Ewo wa ni ti Peter Cech ti o ti dagba ni oju Mourinho, ti Thiabaut Courtois, amule Chelsea ti o wa ni Atletico ti wa wo Mourinho loju.

Mourinho ti fe ki Courtois ti o gba ife eye Zamora -ife eye fun amule ti o dara ju ni Spain- ni emeji, wa si Chelsea ti o je olowo re.

Mourinho ti se ileri fun Courtois wipe ki o ba bo ni Chelsea pada o, ohun ni o ma lo ni gbogbo sa ti o n bo, nitori ohun ma ta Peter Cech ti egbe agbaboolu pupo fe ra.

Nkan ti o dun Mourinho ju ni igba ti Atletico ru ofin adehun won lati lo Courtois ni Champions League sa ti o koja.

Courtois ni enikeji lati Atletico ti o n lo si Chelsea leyin Diego Costa fun sa to n bo.

Mourinho si ti mo wipe dandan ni ki ohun gba ife eye ni sa yi.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Eru Nigeria ti n ba Aguero


“Egba mi! Gbogbo eyan ni o ma n so wipe egbe ti Aregentina wa ni World Cup lo rorun ju, bawo ni e se ma so be nigba ti Nigeria wa nibe, awon ma ni iko agbaboolu to dangajia ju ni Africa, o ma le gan o.

Eyi ni oro ti Sergio Aguero ba awon oniroyin ‘Times of India’ so.

Argentina je orile ede ti awon ati Nigeria ma n saba pade ni World Cup, Nigeria ko si fi igba kan naa ri.

Messi ti o je okan ninu awon ti o dara ju ninu boolu afesegba na ko gba ami ayo wole lodo Nigeria ri ni World Cup.

Nipa boya Argentina le gba ife eye na, Aguero ti o sese pada lati egbo ipalara re so wipe “o da mi loju wipe a le gba World Cup yi, niwon igba ti Lionel Messi, agbaboolu ti o dara ju lagbaye wa ni egbe wa, ohun gan ni o je ki a wa ni World Cup bayi.

Gbogbo alayo wa ni won dara, eni ati Lavezzi si feran lati gba ayo wole gidi gan, pelu iranlowo awon alayo to ku.

Aguero pari oro re pelu “ara mi ti ya daadaa lati igba ti mo ti ba Manchester City gba ife eye Premier League.

Iran, Bosnia, Nigeria ati Argentina ni won jo ma wako ni iko kinni ni World Cup.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Real Madrid je Tottenham ni gbese fun Modric ati Bale


Eni ti o ba wo boolu asikagba Champions League laarin Real Madrid ati Atletico Madrid, a ma ri Aare Tottenham nibe, ogbeni Levy.

Ko wa lati ti awon alayo re tele leyin nikan o, o wa lati le soro adehun ti Tottenham ati Real Madrid so tele ni.

Nigba ti Real Madrid ra Modric ni owo won, won ko sinu adehun wipe milionu meje pon, ni Madrid ma fi kun owo Modric ti Madrid ba de asikagba Champions League.

Milionu mejo ni o wa ninu adehun na, wipe Madrid ma san fun Tottenham ti Bale ba bawon gba ife eye na.

Milionu meedogun ni Real Madrid ma san fun Tottenham bayi nipa se adehun egbe mejeeji.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Ancelotti fe di akoni moogba Italy


Odun mewa, lati 1981 titi de 1991 ni akoni moogba Real Madrid, Carlo Ancelotti fi gba boolu fun orile ede italy, o si gba ami ayo kan pere wole.

O ti fi ero okan re han nigba ti o n ba awon oniroyin soro leyin igba ti Real Madrid gba ife eye Champions League.

“Idunu akoni moogba gbogbo ni ki o ko orile ede re ni boolu gbigba”

“Sugbon bi mo se n ri alayo ko ni boolu ni ojoojumo ni o n dun momi bayi, mo n gbadun isesi emi ati alayo mi.

“Ti faaji bati su mi, maa pe awon adari boolu orile ede Italy FIGC, iyen ti Cesare Prandelli ba feyin ti o, lati di akoni moogba Italy.

Abolade Olajuwon Ryan.

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Real Madrid san owo die fun Aguero


Iwe iroyin ‘Daily Star’ ti tu asiri Real Madrid nipa owo ti won san le lati fun Manchester City lati ra Aguero.

Milionu pon ogota ni owo ti Real Madrid ko le.

Nigba ti Suarez ko lati gba fun won, ni won koju si omo Argentina na.

Real Madrid ati Atletico Madrid ni adehun wipe awon ko ni ta alayo won fun arawon, iba sebe, aare Real Madrid, Florentino Perez ti fe gbe Aguero tipe tipe.

Real Madrid ti setan lati re agba iwaju, niwon igbati Morata ti setan a ti lo.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Barca ti je ki egungun Neymar le ju tele lo – Brazil


Gbogbo atileyin ati agaga ota Neymar, omo orile ede Brazil to n gba boolu fun Barcelona, ni o mo wipe ti alayo ba fi owo kan Neymar lasan, ile ni.

Neymar je eni ti o ma n tete subu gan ninu ere boolu. Eyi je be nitori, nigbati o wa ni Brazil, ojusaju po fun gan nitori o lenu gan.

Nigba ti o de Spain, Barca yi owo re pada, awon alayo La liga gba ese re pa, eyi ti wa je ki egun re gbo daadaa.

Ile ti Neymar pada si fun World Cup ni okan ninu awon akoni moogba Brazil, Paulo Paixao, so wipe “a ni igbekele ninu Neymar, Barcelona ti o lo ti so di alayo to dara ju tele lo.

“O ti le taka pelu awon to o dangajia ju ni agbaye.

Neymar ti o jeun si eke pelu kilo meta nigba ti o ni ipalara ni Paulo ni “ipalara naa ti jina, Barca toju re daadaa.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Oga Manchester United ti Ku!


Olowo tabua, omo orile ede America, ti o ni egbe agbaboolu Manchester United ati Tampa Bay Buccaneers, ogbeni Malcom Glazers ti ku o.

Omo odun aarundinladorun ni o file bora bi aso.

Malcom ya owo ki o to ra Man Utd ni, awon atileyin egbe na ko fibe nife re nitori gbese ti o je ki egbe naa ko si.

Sugbon, gbese owo ti o fi ra Man Utd, owo na ti di ilopo meji bayi, lati bilionu kan, ati abo dollar, o di bilionu meji dollar, o le ni die.

Premier League maarun ati Champions League kan ni Man Utd ti gba lati 2005 ti o gba aga na.

Ounfa iku re ni enikeni ko mo.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Alex Ferguson fe ki Ancelotti dari Man Utd


Ni igba ti Sir Alex Ferguson fe kuro ni Manchester United, o fi owo ara re mu ara ilu re, David Moyes, lati ropo re ni idi ise na, nkan ti a gbo niyen o.

Aare Real Madrid, Florentino Perez, je ki a mo wipe “David Moyes ko ni Ferguson koko fe ki o ropo re ni Man Utd”

“Ferguson pe Ancelotti lati di akoni moogba Man Utd nigbati o wa ni PSG, sugbon, Ancelotti wi fun wipe, ohun ti se ileri lati di akoni moogba Real Madrid.

Ancelotti ti siseni Enland ri, bii akoni moogba Chelsea, o gba ife eye Premier League ati FA cup, sugbon won padanu Champions League si owo Man Utd.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Real Madrid ati Sevilla ma pade ni ile Gareth Bale


Alayo Real Madrid, ti o je alayo ti o won ju ni agbaye ti won ra ni milionu pon ogorun, ogbeni Gareth Bale, ma pada si ilu re.

Omo orile ede Wales ni Bale, ilu Cardiff, ni a ti bi i.

Bi asa ati ise ajo UEFA, egbe agbaboolu ti o ba gba ife eye Champions League ati Europa League maa jo wako ninu idije ti a n pe ni UEFA Super Cup.

Real Madrid ati Sevilla ti won je egbe agbaboolu ni Spain, ni won jo ma koju ija si arawon ni ilu bibi Gareth Bale, Cardiff.

Ojo kejila, osu kejo, odun ti a wa yi i, ni ifese won ese naa ma a waye.

Bayern Munich ni egbe ti o gba keyin, nigba ti won fi oju Chelsea gbo ile ni sa ti o koja.

Abolade Olajuwon Ryan

Ese ti kika.

Ejowo e ma gbagbe lati feran wa lori facebook @sports in yoruba Fun alaye, isina ati imoran,
ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com