Guardiola jewo asise re ni Bayern


Akoni moogba Bayern Munich, ogbeni Pep Guardiola ti jewo wipe ipadanu ti o buru ju, ti o si dun ohun ju lati igba ti ohun ti n se ise akoni moogba.

“E ma da awon alayo lebi o, emi ni mo se asise, ti o fa ipadanu wa ninu idije toni.

“Ti o ba je wipe a gba boolu dara dara ni, iya yi ko ni waye.

“Amoo ti enikeni ba gba boolu bi a se gba boolu lo ni, o di dan dan ki o je buruku iya lodo Real Madrid.

“A ko bere daadaa rara, a ko n gbon ni, eyi de waye nitori bi mo se ni ki awon alayo mi gba boolu ni.

“Emi ni mo se asise, emi ni ki e da lebi.

Real Madrid ko na Bayern ni ayo merin si odo ri ni Germqny afi ano ojo isegun.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan.

Fun asoye,asise tabi imoran kankan, ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Advertisements

Courtois ma gba boolu akoko lori papa oloWo e


Ko n se nkan tuntun lati gba boolu lori papa olowo re, amoo, ejo lowo ninu eleyi.

Thiabaut Courtois, ti Chelsea je olowo re, ti won ra ni odun 2011 ni Genk. Ojo ti won ra, won ri wipe o si kere, won wa ro lapapo lati ya Atletico fun odun kan.

Odun kan pari, won te siwaju ninu adehun won lati fi odun kan kun.

Igbati odun meji pari, adehun won tu wo, odun adehun na tesiwaju pe meta.

Atigba ti Chelsea ti ra, ko i ti wo aso Chelsea gba boolu ri.

Eni ti o ma gba boolu ni ori papa Chelsea ni Stamford Bridge, olowo re, Chelsea ni o ma ko oju ija ti.

Awon atileyin Chelsea ma ri fun igba akoko eni ti o je goli won ni ojo iwaju bi o se ma dangajia to ni ori papa re.

Amoo o, ko n se igba akoko ti o ma fi oju olowo re gbole re, ninu UEFA Supercup odun meji seyin, o se ise to wuni lori lati je ki eyin Chelsea gbole, nigba ti Atleti na Chelsea ni ayo merin si eyo kan.

Ale yi ni ifese won ese na ma waye.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan

Fun asoye,asise tabi imoran kankan, ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Schurrle dahun si Boolu Chelsea ti ko fanimora


Gbogbo eyan ni won ti se idajo wipe bi egbe Chelsea se n gba boolu ko fanimora, ko si fani lokan rara.

Pelu bi boolu won ko se fanimora na, wo n se aseyori ninu idije won.

Nkan ti won so ni wipe Chelsea ko jade gba boolu, won teba sile ni.

Pelu gbogbo re, ipo keji ni Chelsea wa ni English Premiership.

Ohun ni o je ki omo Chelsea kan, Andre Schurrle, so oro yi.

“Eni keni ti o ba so ipe boolu wa ko fanimora, ojowu ni o.

“Ki awa ti jawe olubori ni o se koko ju ninu idije boolu afesegba yi.

“Ewo ni ki boolu fanimora, ki eniyan si padanu idije na, ko n se nkan ti o da. Ohun ti o se koko ni ki a ti jawe olubori.

“Ohun ti akoni moogba wa, Mourinho ba so fun wa ni ama n se.

Chelsea ma ba egbe Atletico wa ko ni eni ojoru ninu idije Champions League.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan.

Ronaldo ya iwe Messi


Ti aba wo inu iwe iranti, iyen ti UEFA Champions League, ama ri wipe Messi ati Jose Altafini ni won ti gba ami ayo wole ju ni sa kan.

Ami ayo merinla ni won ti jo gba wole ni sa kan.

Ko si alayo ti o gba iru re wole ri ni sa kan soso afi ni ano ode o ni ti ami ayo Cristiano wo merindinlogun.

Ori merinla ni Ronaldo wa tele, ayo meji ti o gba wole ninu merin ti Real Madrid na Bayern Munich, je ki o je alayo kan soso ti o wa ni agbaye to gba ami merindinlogun ni sa kan ninu idije Champions League.

Oseese ki ami ayo yi poju merindinlogun lo, nitori idije ipari si wa ti won ma gba ni Lisbon.

Messi ni o wa ninu iwe iranti tele, Ronaldo lo wa nibe nisin.

Ese ti kika.

Abolade Olajuwon Ryan

Fun asoye,asise tabi imoran kankan, ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com

Real Madrid tu asiri Bayern Munich ni oga Bayern so


Igba yi ni odun ti o koja ni Bayern Munich se dende iya, ayo meje si odo ni Bayern na won lapapo.

Real Madrid ti ba won ko iya won pada ni igba ti won na Bayern ni ayo merin si odo ni Allianz Arena.

Ose ti o koja ni Real Madrid na Bayern ni ori papa Santiago Bernabeu pelu ayo kan si odo.

Igba na ni oga patapata Bayern, ogbeni Rummenigge leri pe ina ma jo ni ojo isegun ano. Ojo ni o ro ki idije na to bere o.

Rummenigge tun leri wipe iya ti Bayern ma fi je Madrid ma koja iya orun apandi.

Leyin iya ti o peye, iya na ti jeki o yi ohun pada, o so wipe Real Madrid ti tu asiri Bayern leyin ayo marun si odo lapapo ti Madrid fi eleya egbe re se.

Akoni moogba Bayern, Pep Guardiola na jewo wipe osi ati iranu ni egbe re gba lana, ki se boolu rara.

Akoni moogba Real Madrid, Ancelotti, so wipe asepe ni ise awon alayo re se lati jawe olubori Bayern Munich.

Odun 2002 ni Real Madrid gba ife eye Champions league gbeyin, ele kewa ni won fe gba yi nigba ti won ba koju ija ti ikan ninu Atletico Madrid ati Chelsea ti o ma waye ni eni ojoru.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan

Dani Alves ta ogede fun araye.


Alawo dudu, omo orile ede Brazil, ti o n gba boolu jeun ni egbe Barcelona, ni omo alu sekere fun Villareal so ogede lu ni ijeta ti o si bo je.

Alves ti ri ifowosowopo agbaye lori jije ogede na.

Gbogbo awon ara ilu re ti won gba boolu jeun ni won ti se aworan irawon pelu ogede lati fi han wipe awon wa leyin re.

Aare ilu Brazil, Dilma Rouselff ti so wipe iwa akitiyan ni Alves se lati je ogede na, o si pinu wipe awon ma ja lati ma je ki iru re waye ni ideje boolu agbaye ti won ma gba ni Brazil.

Aare FIFA, Sepp Blatter juba fun iwa agba ti Alves wu nipa jije ogede na.

Awon abojuto eto boolu ni Spain ti yoju si isele na, won si ti ri eni ti o so ogede na, won ti daduro wipe koni le wo boolu titi o ma fi ku mo ni ori papa. O seese ki won ran lo si ewon pelu.

Isele yi ti sele si awon agbaboolu Roberto Carlos, Balotelli, Eto’o ati bebelo.

Balotelli so nigba tire wipe ohun ma pa enikeni ti o ba tu se iru re si ohun ni.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan.

Ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com tabi (234)7088233391

Didirin ni emi ati Real Madrid ni Ancelotti so


Oni ni, koni di ola, ni ese ikeji Semi Final ni idije Champions League.

Ancelotti mu omo egbe re ti won ra ni milionu lona egberun pon, Gareth Bale, lati ba awon oniroyin soro.

Okan re bale ju Guardiola lo ni iwaju awon oniroyin na.

“Egbe mi ko ni joko si ile, ama jade lati gba ami ayo wole ni, nitori wipe nkan ti o ma fun wa ni ifokan bale ti o pe ye niyen.

“Inu mi ma dun ti o ba je wipe egbe mi lo ma gba ife eye na, idije ifese won ese ti o ma le gan ni.

Guardiola ni, ohun ka ni ibi kan wipe egbe Real Madrid ni lokan wipe awon ti jawe olubori layi gba ese keji idije naa, Ancelotti dahun bayi.

“Didirin ni emi ati egbe mi ti aba file ro wipe ati jawe olubori ninu ifese won ese yi layi ti gba rara.

Akoni moogba Bayern, Pep Guardiola so tele wipe elere bi ti okere ni awon alayo Real Madrid, Ancelotti ti fun ni esi wipe ooto ni ohun ti o so.
“Ooto ni wipe awon alayo mi dangajia gan, ko da Olorun bun wa pelu awon alayo ti ara won pe gidi ni.

“Awa ko ni yi owo pada ninu bi ase ma gba boolu pelu Bayern, o seese ki a fi eyan meta si iwaju tabi eyan meji, amoo, ireti wa ni wipe ki a jade lati gba ayo wole ki o le rorun fun wa.

Real Madrid ni o jawe olubori ni ese kini idije na pelu ayo kan si odo.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan

Ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com tabi (234)7088233391

Iya tafi je Barca ni odun to koja ni ama fi je Real Madrid


Omo orile ede Nigeria ti o n gba boolu fun orile ede Austria, David Alaba ti ranse ikilo si Real Madrid.

“Ema gbagbe wipe Barcelona wa si ori papa wa ni odun ti o koja, a de na won, tori-torun, tifun-tedo.

“Iya ti afi je Barca ko ma n se kekere, Iru re ni ama se fun egbe Real Madrid ni odun yi.

Ayo merin si odo ni Bayern na Barca ni sa ti o koja, ki won tu to na won ni ayo meta si odo ni Camp Nou ti o je ori papa Barca gan gan.

“Ope lope awon omo atileyin wa ti won po ni ojo na, awon ni won lu ilu fun wa ti ori wa fi n wu lati le na Barca, inu wa ma dun ti won ba jade wa lu ilu fun wa ni ote yi.

Atileyin Bayern Munich ni idije kan lori papa Allianz arena ma n to eyan egberun lona ogota.

“O wu wa lati de idije ipari ni Lisbon.

“Ninu idije Champions League, Manchester City ti na Bayern mo ile ni sa yi, beni Borussia Dortmund ti na won ni ayo meta si odo ni Bundesliga.

Ese ti kika

Abolade Olajuwon Ryan

Ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com tabi (234)7088233391

Ronaldo ran ise aramanda si Bayern


Real Madrid se ise won daadaa ni ojo abameta nigba ti won ko iya fun egbe Osasuna.

Opelope Cristiano Ronaldo ti o gba ami aramanda meji wole ninu merin si odo ti won naa egbe na, Sergio Ramos ati Dani Carvajal ni won gba ami meji ti oku wole.

Nitori idije Champions League ti won ma ba Bayern gba ni ojo isegun, akoni moogba Real Madrid ni ki Pepe, Benzema, Coentrao ati Bale simi.

Ronaldo ti o sese de lati isimi ipalara fi han wipe ara ohun ti dangajia, fi han ki iseju mewa to pe pelu ami aramanda ti o gba wole.

Iyen ni o fi ranse si Bayern wipe ki won ma ro wipe Real Madrid ma joko si ile bi ese akoko o, iru aramanda goolu ti ohun gba wole ni ojo abameta ni ohun ma fi fun won ni ebun ni ojo isegun.

Ronaldo ti gba ami ogbon wole ni La liga sa yi, ohun deni o n siwaju ninu awon ti o ti gba ami ayo wole ju. Diego costa ati Messi ni won n tele.

Ese ti kika,

Abolade Olajuwon Ryan

Ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com tabi (234)7088233391

Dani Alves je ogede lori papa


Opelope asebi ni Dani Alves so nigba ti awon omo atileyin Villareal so ogede si lori papa, eni na fi ogede na bu nitori o je alawo dudu, won fi we obo ni.

Kaka ki o binu, o dupe lowo eni na, o so wipe ogede na sise gidi gan lara ohun, ogede na ni o fun ohun ni agbara ti o fi gba boolu si ori omo villareal, ti o si kan si ile ara re.

“Emi o mo eni ti o so ogede lumi, nkan bayi ko sese ma sele.

“Odun mokanla ti mo ti lo ni orile ede Spain ni awon adato lenu won yi ti n se be.

Ayo meta si meji ni Barcelona na Villareal.

Ese ti kika

Abolade Olajuwon Ryan.

Ele kan siwa ni sportsinyoruba@gmail.com tabi (234)7088233391